Pakistan: Àgbájọ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani

Agbarijọpọ àwọn eeyan kan ti ṣekupa ọkunrin kan ni aaringbungbun Pakistan lori ẹsun pe o dana sun awọn abala Kurani kan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti ọwọ ofin mu ọgọrin eeyan lori iṣẹlẹ naa to waye lọjọ Abamẹta lẹkun Khanewal ni Punjab.

Iroyin kan tiẹ sọ agọ ọlọpaa ni ọkunrin naa wa ki awọn ero kan to lọ ji gbe lati ṣekupa a.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe oku ọkunrin naa fun awọn ẹbi rẹ fun eto isinku lọjọ Aiku.

Olootu ijọba Pakistan sọrọ lori iṣẹlẹ naa

Ẹwẹ, olootu ijọba orilẹede Pakistan, Imran Khan ti ṣeleri pe iwadii yoo waye lori iṣẹlẹ naa.

Khan ti wa beere lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa lati foun ni orukọ awọn ọlọpaa to yẹ ki wọn daabo bo ọkunrin naa ṣugbọn ti wọn kuna lati ṣiṣẹ wọn.

Olootu ijọba Pakistan ni ijọba oun ko ni fi oju ire wo ẹnikẹni to ba n tapa sofin ilẹ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ti waye

Ọkan lara awọn ọlọpaa, Munawar Hussain ṣalaye pe niṣe lawọn kan ri pe ọkunrin naa ko le sọrọ mọ nibi ti wọn ti de e mọ igi.

Hussain ni ''awọn eeayan ilu naa mu kondo, aake ati irin dani eleyii ti wọn fi pa ọkunrin naa.

Ori igi kan ni wọn gbe oku rẹ si.

Munawar Gujjar, to jẹ ọga ọlọpaa ni Tulamba nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ fawọn akọroyin pe ọkunrin ọhun ti larun ọpọlọ fun bi ọdun mẹdoogun.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oṣu meji tawọn eeyan kan lu ọga ileeṣẹ kan pa ni ileeṣẹ Sri Lanka kan ti wọn si tun dana sun un lori ẹsun pe o sọrọ idi tako ẹsin niluu Sialkot eyi to wa ni ẹkun Punjab kan naa.

Ijiya fun ẹni to ba sọrọ odi si ẹsin Islam ni Pakistan le jasi iku.

Amọ, ọpọ lo ti bu ẹnu atẹ lu ofin naa pe idẹyẹsi lo jẹ si awọn ti kii ṣe ẹlẹsin Islam.

Ofin yii ni wọn n lo lati yanju ede-ai-yede to ba ṣẹlẹ laarin awọn eeyan ṣugbọn ti ko ni ohun kan ṣe pẹlu ẹsin.