Yaba building collapse: Ilé alájà mẹ́ta dàwó ní Yaba nílùú Eko, àwọn èèyàn há sábẹ́ ilé náà

Ilé alájà mẹ́ta kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ti dàwó ní òpópónà Akanbi Crescent, Yaba, ìpínlẹ̀ Eko.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, ilé náà dàwó lé ilé mìíràn tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

Àwọn ènìyàn wà nínú ilé náà lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú rẹ̀ ní lára ilé náà ti dàwó lọ́dún tó kọjá ṣùgbọ́n tí èyí kò díwọ́ iṣẹ́ ilé náà dúró.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa laipẹ.