Sunday Igboho: Agbekoya ní òun kò le gbà kí Igboho tún lo osù mẹ́fà si ní àhámọ́, àwọn yóò fi agbára Yorùbá gbe jáde

Lẹyin Osu meje ti oloye Sunday Adeyemi, ti ilu mọ si Sunday Igboho ti wa ninu ahamọ ni orilẹede Benin Republic, Iya oloye naa, Arabinrin Adeyemo ti wa ni idubulẹ aisan lọwọ bayi nitori ahamọ ọmọ rẹ.

Ẹgbẹ Agbekoya lo sisọ loju ọrọ yii lasiko ti wọn n se ipade akọroyin kan nilu Ibadan, eyi ti BBC News Yoruba peju si.

Ohun to fa ipade akọroyin naa ni lori erogba ẹgbẹ Agbekoya lati pe fun idasilẹ Sunday Igboho tabi ki wọn lo agbara wọn lati yọ ajijagbara naa ni ahamọ.

"Ahamọ ọlọjọ pipẹ ti wọn fi Sunday Igboho si, ti fa aisan si Iya rẹ lara, ti Iya naa si ti wa ni idubulẹ aisan bayi.

O to ko rẹ iya yẹn, ọmọ rẹ ko ṣẹ, mu si ahamọ, se ka wa fi silẹ ni?

Ọrọ yii ko ni le wọ, ka so aja mọlẹ, ka so ẹkun mọlẹ, ka wa fi iru ẹkun le aja lọwọ, ko seese.

Ki ijọba tun Igboho silẹ tori bi bẹẹ kọ a jẹ ki wọn mọ pe ogun wa, agbekoya si ni asiri lati tu oloye Sunday Igboho silẹ ni ahamọ.

Bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ìyá Sunday Igboho wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn nítorí kò rí ọmọ rẹ̀ láti ọjọ́ yìí.

Fún ìdí èyí, a kò le gbà kí Igboho tún lo oṣù mẹ́fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n orílẹ̀ èdè olómìnira Benin.

A lo oogun ibilẹ lati yọ Sunday Igboho ni ahamọ, ọrọ ẹnu kọ:

Aarẹ fun ẹgbẹ Agbekoya kaakiri agbaye. Oloye Kamarudeen Okikiola Aremu ti wa fi ọwọ sọya pe awọn yoo lo oogun ibile lati yọ Igboho kuro ninu ahamọ to wa ni orilẹede.

Aremu sọ pe Igboho ko sẹ si ofin ilu Benin Republic amọ bi iyanjẹ ba ti pọ ju, Ọlọrun maa ran awọn eeyan kan dide fun idande ẹni ti wọn yan jẹ.

"Ọlọrun lo ran Agbekoya dide tori bi wọn se fi Igboho si ahamọ lai gbe lọ sile ẹjọ ko boju mu, ibi ti maa pa ọ wa, naa ni maa gba ọ wa.

Ọlọrun to da agbara, o da kaakiri ni, agbara ti Yoruba naa ni, Ki lo de ti a ko pamọ.

Ó tẹ̀síwájú pé "ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ìhàlẹ̀ lásán, ohun tí a fẹ́ ṣe ni, ó ní ọgbọ́n tí Yorùbá fi máa ń lò láti gbé nǹkan jáde, ẹni tó bá ní kò sí òògùn, òògùn ń bẹ o".

"Nígbà tí a kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ yẹn, oríṣìíríṣìí ìpè la gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà Yorùbá àti àwọn ọba láti má jẹ̀ ẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà di wàhálà."

O wa dupẹ lọ́wọ́ awọn ọba ati asaaju ilẹ Yoruba to n se atilẹyin fun wọn lori idande Sunday Igboho.

A ko fi ara mọ pe ki Sunday Igboho tun lo osu mẹfa si ni ahamọ:

Bakan naa ni ẹgbẹ Agbekoya ti ke si ijọba Naijiria lati lọ jiroro pọ pẹlu ijọba Benin ki wọn le tu Sunday Igboho silẹ.

Wọn ni yoo dara ki àjọsọ wa laarin ijọba orilẹede Naijiria pẹ̀lú ìjọba orílẹ̀ èdè olómìnira Benin lójúnà àti tú Sunday Igboho kúrò ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà.

Agbẹkọya ni oun ko fara mọ ki ajijagbara naa tun lo osu mẹfa miran si ni ahamọ, ko le seese.

"Ẹ ba ko gbogbo Sọja orilẹede Benin si ahamọ ibi ti Sunday Igboho wa, a gba silẹ́, tẹ ba tete fi silẹ pẹlu idajọ ododo.

Ko seese ki Sunday Igboho si wa ni ahamọ, a ko dunkooko o, a tun n tmọ pe o wa lati ọkan wa ni."

Ẹ se atunto Naijiria, ki oun gbogbo pada bọ sipo:

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìpè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation, aarẹ ẹgbẹ Agbekoya ní ìjọba tí Buhari bá ṣe àtúntò tí àwọn ń bèèrè fún, tí ìjọba ṣe ohun gbogbo tí ara ilu n fẹ́, tí ìyà kò jẹ ara ìlú, kò sí ìdí tí awọn yoo fi ní kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà pín.

O wa salaye pe awọn kọkọ n fẹ itusilẹ Igboho ni ahamọ na, ki awọn to le sọ boya awọn yoo tẹsiwaju pẹlu ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Ìpàdé ọ̀hún ni àwọn aṣojú Àgbẹ́kọ̀yà káàkiri ilẹ̀ Yorùbá péjú pésè síbẹ̀.