You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ibadan Robbery Attack: Gbogbo ojú ọnà tàwọn adigunjalè lè gbà lá ti di- Komisana Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ti tako iroyin to gbode pe ọlọpaa meji ku ninu idigunjale to waye lonii ni Ilu Ibadan.
Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ngozi Onadeko, sọ pe ko si ootọ ninu iroyin naa ati pe awọn ọlọpaa lo pa ọkan ninu awọn igara ọlọsa yi.
Lasiko to n ba awọn akroyin sọrọ lo fidi ọrọ yi mulẹ to si ni gbogbo oju ọna to wọ ipinlẹ Oyo tabi to jade tawọn adigunjale yi le gba lawọn ti di.
O ni ko ni pẹ tọwọ awọn yoo fi tẹ wọn.
O fi kun pe ''ṣebi ẹ ri awọn ikọ Amọtẹkun, awọn ọlọpaa, gbogbo wọn ni wọn jijọ n ṣiṣẹ papọ ki a baa le ri awọn araabi mu ka si mọ ohun to ṣẹlẹ lonii''
''Mo maa fun yin ni ẹkunrẹrẹ iroyin ti a ba mọ pato nkan to ṣẹlẹ''
Onadeko tẹsiwaju pe ọkan lara awọn ọlọpaa to sin ọkọ agboworin naa pa ọkan ninu awọn adigunjale yi ti wọn si gbe oku akẹgbẹ wọn salọ.
''Ko si ẹnikẹni to ku.Ni ododo mo ṣi n gbiyanju lati mọ ohun to ṣẹlẹ ni. Sugbọn mo le fi da yin loju pe awọn ọlọpaa meji faragbọta ni itan wọn.''
O ni ki awọn araalu jẹ ki awọn ṣe iwadii tan, lẹyin igba naa awọn yoo ṣọ pato ohun to ṣẹlẹ.
Ohun taa gbọ tẹlẹ ni pe Aráàlú mẹ́rin, ọlọ́pàá méjì bá ìṣẹ̀lẹ ìdigunjalè lọ ní Ibadan l'Ọ́jọ́bọ
Ọlọrun ma jẹ ka rin arinfẹsẹ si, ma jẹ ka rin ni ọjọ ti ebi yoo pa ọna.
Adura nla ni adura yii, bi o tilẹ jẹ pe adura naa gba fun awọn eeyan kan nilu Ibadan lonii, amọ ko gba fun awọn eeyan miran.
Idi ni pe lootọ ni ori ko awọn eeyan kan yọ lasiko ti awọn adigunjale se ọsẹ ni ikorita Idi Ape nilu Ibadan amọ awọn eeyan mii ba isẹlẹ naa lọ.
- Mo ní ẹ̀ṣọ̀ ara tó lé ní ₦300m láyé àkọ́kọ́, ti mo ń gbé òògùn olóró
- Ìjọba Oyo gba adé lórí àwọn baálẹ́ àti Mogaji tí Ajimọbi sọ di ọba ní Ibadan
- NNPC di ẹ̀bí ayédèrú epo tó wọ Nàìjíríà ru iléeṣẹ́ mẹ́rin
- Ta ló gbé òkú èèyàn tó ti jẹrà sínú ilé àkọ́patì nílùú Oyo?
- Ìjọba Oyo àti iléeṣẹ́ amúnáwá wọ̀yá ìjà torí gbèsè tí wọn jẹ ara wọn
- Akẹ́kọ̀ọ́ fásítì OAU dèrò ọ̀run nígbà tó já sínú kòtò ilé ìgbẹ́ ‘soakaway’
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe awọn adigunjale mu ẹmi ọlọpaa meji lọ ati araalu mẹrin lọ lasiko ti wọn digun jale ladugbo naa ni Ọjọbọ.
Akọroyin BBC Yoruba to se abẹwo si adugbo Idi Ape nibi ti isẹlẹ naa ti waye salaye pe se ni ọpọ eeyan tun fi ara pa ninu isẹlẹ idigunjale naa.
Bawo ni isẹlẹ idigunjale naa se waye?
Awọn adigunjale naa ni wọn n gbinyanju lati ja ọkọ banki kan to n gbe owo rin, lẹyin o rẹyin, wọn ko owo inu mọto naa, ti wn si fi ẹsẹ fẹ.
Se ni awọn adigunjale naa n yinbọn laibikita, ti ọpọ ọta ibọn si wa ni ara ọkọ ọlọpaa to n tẹle ọkọ banki agboworin naa.
Asiko yii si ni ẹmi ọlọpaa meji to wa ninu isẹlẹ naa bọ nitori ọta ibọn to ba wọn.
Lara awọn eeyan to fi ara gba ọta ibọn ni awọn eeyan to wa ninu ọkọ wọn, ti ina to n dari ọkọ ni oju popo mu mọlẹ lati lọ.
Bakan naa la ti baba kan to wọ ankara alawọ ewe ati omi aro, ti ẹjẹ kun ara rẹ, pẹlu ọkunrin ọlọkada kan to n yi ninu agbara ẹjẹ nitori ta ibọn to fi ara gba.
Isẹlẹ yi lo da omi alaafia adugbo naa ru, ti awọn eeyan si n sa asala fun mi wọn,bẹẹ ni sunkẹrẹ fakẹrẹ wa loju popo naa.
Ohun gbogbo ti pada bọ sipo ni adugbo Idi Ape lẹyin isẹlẹ idigunjale:
Awọn osisẹ ọlọpaa ti de si ibi ti isẹlẹ naa ti waye, ti wọn si ti gbe awọn eeyan to fi ara gba ọgbẹ ọta ibọn lọ sile iwosan fun itọju.
Bakan naa ni wọn ti gbe awọn oku ti ọta ibọn awọn adigunjale naa pa lọ sile igbokusi.
Nibayii, nigba ti ikọ iroyin BBC Yoruba yoo fi kuro ni agbegbe naa, ohun gbogbo ti pada bọ sipo, ti awọn eyan ati ọkọ si ti n lọ lai si idiwọ.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.