19 month old pupil flogged by teacher: Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọmọ ọdún kan àti oṣù méje pa ní ìpínlẹ̀ Delta

Awọn ọlọpaa nipinlẹ Delta ti mu olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan to lu akẹkọọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun kan ati oṣu meje pa.

Olukọ naa, Emeka Nwogbo, ni iroyin sọ pe o jẹ ọmọ ẹni to ni ile ẹkọ naa to wa nilu asaba.

A gbọ pe olukọ ọhun fi ibinu fi ẹgba lu ọmọ naa, Obina Udeze, nitori pe o n fi omi ṣere titi aṣọ rẹ fi tutu.

Awọn iroyin kan ti ẹ sọ pe ẹgba mọkalelọgbọn ni wọn lu ọmọde naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Delta, DSP Dafe Bright to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Pidgin sọ pe ẹsun ipaniyan ni wọn o fi kan olukọ naa.

O ni ọmọ kekere naa dubulẹ aisan lẹyin ti olukọ rẹ lu u tan, eyi to mu ki wọn o sare gbe lọ si ilewosan ijọba nibi to ti n gbaitọju.

Amọ, o ku ni owurọ ọjọ Satide, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

DSP Bright sọ pe laipẹ ni wọn o gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa gba beeli afurasi, ṣugbọn wọn tun pada mu lẹyin ti ọmọ naa ku.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, iroyin bi awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama ati alakọbẹrẹ ṣe n ku tabi farapa, wọpọ ni Naijiria.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Iya ọmọde naa, Gift, to ba iwe iroyin Punch sọrọ, ni oun ri àpá ẹgba lara ọmọ oun nigba to de lati ile ẹkọ lọjọ Aje to kọja.

Arabinrin naa sọ pe oun lọ si ile ẹkọ naa lati beere idi ti wọn fi lu ọmọ oun bẹẹ, amọ esi ti ẹni to ni ile ẹkọ fun ko dun mọ ninu rara.

O ṣalaye pe nibi ti oun ti n pada sile, ni awọn akẹkọọ kan ti sọ fun oun pe niṣe ni wọn so ọmọ oun ni ọwọ ati ẹsẹ lasiko ti wọn n lu u, nitori pe o ni ebi n pa oun.

"Ara ọmọ naa gbona titi ilẹ ọjọ keji fi mọ ni, titi oun fi gbe lọ sile iwosan, nibi to ku si."

Awọn akẹkọọ ko ṣẹṣẹ ma a ku tabi farapa nile ẹkọ

Laipẹ yii ni iroyin iku Sylvester Oromoni, akẹkọọ Dowen College nilu Eko jade.

Awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ni iroyin sọ pe o lu u pa, nitori o kọ̀ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.

Ninu oṣu Kinni bakan naa, iroyin sọ pe akẹkọọ ile ẹkọ girama St. Valerian, nilu Onitsha nipinlẹ Anambra, ku lẹyin ti akẹkọọ obirin kan lu u.

Asiko ti olukọ naa n lu Izuchukwu Onwualu, nitori pe ko ṣe iṣẹ amurele rẹ ni ọmọ naa fi ori gba ogiri.

Ọjọ keji lo ku sile iwosan.