You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gabon youth coach arrested: Olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù U-17 ní Gabon dèrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn fífipá bá àwọn agbábọ́ọ́lù ọ̀kùnrin sùn
Olukọni tẹlẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Under-17 ni orilẹ-ede Gabon, Patrick Eyi, ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii nitori ẹsun ifipabanilopọ.
Ọjọ Ẹti to kọja ni ajọ bọọlu orilẹ-ede naa da a duro lẹnu isẹ, lẹyin ti ileeṣẹ to n mojuto ere idaraya sọ pe Aarẹ Ali Bongo ṣapejuwe ẹsun naa gẹgẹ bi eyi to lagbara pupọ.
Ọgbẹni Eyi sọ fun BBC pe oun ko jẹbi ẹsun naa. O ni ọna lati yẹyẹ awọn aṣeyọri oun ni.
Ẹsun ti wọn fi kan-an ni pe o n ni ibalopọ pẹlu awọn ọdọmọkunrin kekeeke to n dari.
- Ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Myanmar ṣekúpa èèyàn 40, wọ́n lu àwọn míì títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lẹ́nu wọn
- Èmi ò ṣetán láti gbẹ̀mí ara mi o, ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ ni pé...- Ibrahim Chatta
- Wọ́n ti iléèwòsàn pa nítorí àwọn àlùjànú tó n fi ipá bá àwọn nọ́ọ́sì lòpọ̀
- Àwọn ọlọ́pàá ti gbé tọkọtaya tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ọmọ oṣù mẹ́fà dí gbèsè tó fi kú
Iwe iroyin The Guardian to jẹ ti ilẹ Gẹẹsi sọ pe agbabọọlu kan to wa pẹlu ikọ ọjẹ wẹwẹ nigba kan, sọ fun ohun pe iwa fifi ipa banilopọ ti n waye fun ọpọlọpọ ọdun ninu ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Gabon.
Agbabọọlu naa sọ pe wọn fi ipa ba oun lopọ.
Lọjọ Aiku bakan naa, wọn tun da olukọni miran duro ni Gabon lori ẹsun fifi ipa ba ọmọde lopọ.
Ẹgbẹ agbabọọlu TP Akwaenbe da Mickala Orphe duro lẹyin ti awọn eeyan fi ẹsun ifipabanilopọ kan lori ayelujara.
Ni bayii, ileeṣẹ eto ere idaraya ni Gabon ti bẹrẹ iwadii lori awọn ẹsun ifipabanilopọ to n waye ninu ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede naa, to si tun sọ fun ileeṣẹ eto idajọ lati tan ina iwadii de awọn ẹka ere idaraya yooku.