You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gernot Rohr VS NFF : Mí o gbà kí NFF yàn lémi lọ́wọ́ ló dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wà-G
Akọnimọọgab ikọ Super Eagles ti tu kẹkẹ ọrọ lori ohun to mu ki iṣẹ bọ lọwọ rẹ.
Ni ọjọ Kejila oṣu yi ni ajọ elere bọọlu kede pe awọn ti ni ko kuro nipo gẹgẹ bi olukọni ikọ naa.
Wọn ni aikaju oṣunwọn ati airibi fidi ifarajin mulẹ laarin awọn agbabọọlu r lo mu ki wọn gbọn yọ lẹnu iṣẹ.
Amọ Rohr ti fesipada to si ni aifaye gba NFF lati yan le oun lọwọ nipa agbabọọlu ti yoo ṣoju ilẹ naa lo da wahala silẹ.
Ninu ifọrwerọ kan to ṣe pẹlu akọroyin ere idaraya Colin Udoh lo ti tu kẹkẹ ọrọ yi.
O ni awọn kan lara awọnb alaṣẹ NFF n duro le oun lọrun lori agbabọọlu ti wọn yan laaye lati ṣoju Naijiria.
''Mo mọ pe ọpọ eeyan lo nifẹ bọọlu ni Naijiria to si ni awọn agbabọọlu ti wọn yan laayo.Mo si mọ pe awọn kan nifẹ si agbabọọlu kọọkan ti wọn fẹ ri lori papa.A jijọ jiroro lori ọr yi''
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe se lootọ lawọn alaṣẹ NFF duro le lọrun laori agbabọọlu ti wọn fẹ, o ni:
''Wọn gba mi ni imọran to pọ.Mo mọ pe awọn a;aṣẹ fẹ ka ṣe aṣeyọri ,gbogbo eeyan naa lo mu erongba ti wọn wa ṣugbọn o ti pọ ju''
Bi NFF ṣé fọwọ́ òsì júwe ilé fún Gernot Rohr
Ajọ elere bọọlu lorileede Naijiria NFF ti gba iṣẹ lọwọ akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Super Eagles, Gernot Rohr.
Atẹjade lati ọdọ akọwe agba ajọ naa lalẹ ọjọ Aiku sọ pe ni kiakia ni ki o fipo silẹ lai si idaniduro kankan.
Balogun ikọ Super Eagles tẹlẹ ri, Augustine Eguavoen ni wọn yan pe ko maa dele gẹgẹ bi oludari ikọ naa.
Gernot Rohr to jẹ ọmọ bibi ilẹ Faranse ati Germany ni akọnimọọgba to pẹ ju lori ipo oludari ikọ Super Eagles.
Nkan bi oṣu mẹrinlelọgọta lo lo lori ipo ki iṣẹ to bọ lọwọ rẹ.
Ikede iyọninipo rẹ ko jẹ tuntun si ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ni Naijiria to ṣe pe wọn ti n reti ki wọn yọ ọ nipo tẹlẹ.
Augustine Eguavoen to wa nipo akọnimọọgba fidihẹ bayi ti dari ikọ Super Eagles tẹlẹ ri ti wọn si gbe ipo kẹta labẹ rẹ ninu idije AFCON to waye ni Egypt lọdun 2006.
Oun ni yoo wa dari ikọ naa bayi gẹgẹ bi wọn ti ṣe n gbaradi fun idije AFCON ikẹtalelọgbọn iru rẹ ti yoo waye ni Cameroon laarin ọjọ Kẹsan oṣu Kini si ọjọ Kẹfa oṣu Keji 2022.