You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Genort Rohr: ìṣẹ nla wa ni iwájú wa
Akoni-moogba ìkọ Super Eagles orílèèdè Nàìjíríà Genort Rohr ti kesi awọn agbaboolu rè láti sọ okun ṣòkòtò wọn dáadáa ní igbaradi dé ìdíje àgbáyé to n bò lónà.
Rohr ni kò sí ayé fún iregbe mọ nítorí iṣẹ nla wa ni iwájú wọn.
Ojú òpó Twitter ìkọ Super Eagles ni o lédè ọrọ náà sí leyin ti iko re fidiremi lowo iko ile Geesi pẹlu ami ayo meji si ọkan.
''Òsé méjì ni o kù ti a o fi gba ifẹsẹwọnsẹ àkọkọ́ wà ní Russia.Kò sí ayé eré mo.a gbọdọ gbaju mọ iṣẹ́ wà"
Alex Iwobi to jẹ́ ọkan lára àwọn agbaboolu Super Eagles Nàìjíríà náà sọrọ lójú Twitter nípa igbaradi wọn.
O ni oun dúpẹ lọdọ awọn alatilẹyin ''tó wà wò wá ní Wembley àti jakejado àgbáyé.Eyi kìí ṣe èsì tí a lérò ṣugbọn a o tèsíwájú ipalemo dé Russia.''
Nàìjíríà yoo koju Czech Republic ni Ọjọọru, Ọjọ Kẹfa, Oṣu yii, ni itesiwaju ipalemo de idije Ifé Ẹyẹ Agbaye, Russia 2018.