Rachael Ayegba: Golí agbábọ́ọ̀lù obìnrin Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ di awakọ̀ bọ́ọ̀sì ní UK

Ọna ọfun, ọna ọrun, bayii ni awọn Yoruba maa n wi.Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Super Falcons orilẹede Naijiria tẹlẹ, Rachael Aladi Ayegba ti di awakọ bọọsi nla lorilẹ ede bayii.Ayegba ṣoju Naijiria ninu idije ere bọọlu agbaye lọdun 2007 lorilẹ ede China.

Bakan naa ni Ayegba ṣoju Naijiria ninu idije ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Afirika lọdun 2006 ati 2008.Ọdun mọkanla ni o fi gba bọọlu jẹun lorilẹ ede Finland ki o to lọ fun ẹkọ olukọni ere bọọlu.Iwe iroyin UK's Evening Standard sọ pe o kere tan awon awakọ bọọsi n N14m lowo oṣu ni UK.Ayegba to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji tiẹ sọ fun iwe iroyin Evening Standard pe bi oun ṣe jẹ agbabọọlu tẹlẹ ri n ran oun lọwọ lati ṣiṣẹ dẹrẹba dara dara.Ayegba ni oun ti maa lọ UK fun họlude tẹlẹ nigba ti oun fi gbabọọlu ni orilẹ ede Finland.Lati agbegbe Victoria si Lewisham bọọsi ti Ayegbe n wa n na lẹyin ọdun mẹta ti o ti n gbe orilẹ ede UK bayii.