Ondo Rape: Pásítọ̀ ní ẹ̀mí èsù ló gbé òun wọ̀ títí òun fi fi ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ lòpọ̀!

Ọwọ ti tẹ pasitọ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, Festus James to fi ipa ba oloyun osu mẹjọ sun ni agbegbe Agbabu nipinlẹ Ondo.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni pasitọ ọhun jẹwọ pe lootọ ni oun ṣe aṣemaṣe naa.

Arabinrin Odunlami ni pasitọ naa lọ si ilu Agbabu lati ipinlẹ Ọyọ lati lọ ṣe isọji agbaiyanu nibẹ ti ọpọ ero si pe jọ.

Lasiko isoji naa ni pasitọ ni ẹmi mimọ kọ si oun pe obinrin oloyun naa ni ẹmi esu pe ki o si tẹle oun lọ gbadura lati yọ ẹmi buruku naa kuro ninu rẹ.

Arabinrin oloyun naa to jẹ ẹni ọdun mejilelogun lo tẹle pasitọ wọ yara to wa ni ''mission house'' to si fi ipa ba a lọpọ.

Pasitọ lasiko to n wi ti ẹnu rẹ fun awọn oniroyin ni ko fi igba kankan sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun naa, amọ o ni oun ko mọ nkan to gbe oun wọ lati hu iru iwa bẹẹ.

O ni wi pe oun ti ba obiinrin naa lopọ tan ki iye rẹ to sọ pe iwa buruku ni oun ṣẹṣẹ wọ tan.

Pasitọ naa ni o dabi ẹni pe ẹmi ẹsu gbe oun wọ, amọ oun ti oun le e sọ ni pe oun ko mọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye afi igba ti oun pari ifipabanilopọ naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa wa fikun un pe awọn n gbe pasitọ James naa lo si ileẹjọ ni aipẹ lati foju wina ofin lori ẹsun ifipabanilopọ naa.