You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Russia 2018: Rohr gbọ́dọ̀ kéde orúkọ àwọn tó ń ko lọ láìpẹ́
Akọnimọọgba ikọ Super Eagles, Gernot Rohr, ti yọ agbabọọlu marun-un kuro ninu awọn ọgbọn to kọkọ gbe jade saaju ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.
Awọn marun-un naa ni Moses Simon ati Junior Lokosa ti wọn jẹ agbabọọlu iwaju, Uche Agbo ati Stephen Eze ti awọn jẹ adilemu.
Aṣọle, Dele Ajiboye ni agbabọọlu karun un ti akọnimọọgba Rohr yọ kuro ninu awọn agbabọọlu ilẹ Naijiria.
Gernot Rohr gbọdọ kede orukọ awọn mẹtalelogun ti yoo ṣoju orilẹ-ede Naijiria nilẹ Russia ko to di ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa ọdun yii.
Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbalejo ikọ Super Eagles nile ijọba l'Ọjọru ki wọn to rinrin ajo lọsi ilu London lọjọ kan naa.
Naijiria yoo koju ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ni papa iṣerẹ Wembley l'Ọjo Abamẹta.
Ki wọn to lọ koju Czech Republic lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii.