Odion Ighalo: Ẹlẹ́sẹ̀ ayò Ighalo ń ronú láti padà sí Super Eagles láìpẹ́

Ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria to n gbabọọlu fun ikọ Manchester United, Odion Ighalo ti sọ pe oun n roo lọwọ lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles.

Ighalo sọrọ yii nigba to n kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lori ileeṣẹ redio Brila FM.

Ighalo kede ifẹyinti ninu ere bọọlu fun Super Eagles lẹyin idije 2019 AFCON to waye lorilẹ-ede Egypt.

Ẹlẹsẹ ayo Ighalo ni oun kede ifẹyinti tẹlẹ nitori Naijiria jina si China nibi ti oun ti n gbabọọlu fun ikọ Shanghai Shenshua.

Amọ, o sọ pe oun le pada bayii nitori ilẹ Gẹẹsi ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti oun n ṣoju wa.

Ṣugbọn o ni oun si fẹ gbaju mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti oun wa bayii.

Lasiko ti ọja rira agbabọọlu ṣi silẹ ninu oṣu kinni ọdun 2020 ni Ighalo darapọ mọ Manchester United lati ikọ agbabọọlu China, Shanghai Shenhua.

Ighalo ti gba goolu mẹrin sawọn lẹẹmẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to lanfaani lati ṣoju Man U ninu rẹ ki o to di wi pe wọn so ere bọọlu rọ nilẹ Gẹẹsi nitori ajakalẹ aarun coronavirus.

Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Man U ti sọ loju opo Twitter pe ohun to jẹ kawọn ṣe adehun tuntun pẹlu Ighalo ni pe o farajin ṣiṣẹ atawọn goolu to ti gba sawọn.

Victor Osimhen lo ti n siwaju ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lati igba ti Ighalo ti fẹyinti.