You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ronaldo Brazil làgbà gbogbo agbábọ́ọ̀lù, kì í ṣẹgbẹ́ ẹ Messi àti Ronaldo- Roberto Carlos
Agbabọọlu Real Madrid tẹlẹ ri, Roberto Carlos ti sọ pe ẹlẹsẹ ayo, Ronaldo Nazario Delima pegede ju Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo lọ nigba to si fi n gba bọọlu.
Ronaldo Delima gba gbajugbaja ami ẹyẹ Ballon d'Or lẹẹmeji, o si tun gba ife ẹyẹ agbaye lọdun 1994 ati 2002.
Ṣugbọn ifarapa leralera lori ookun rẹ ko jẹ ko le gba bọọlu pẹ.
Amọ, o pitu meje tawọn ọdẹ n pa ninu igbo nigba to fi n ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona lorilẹ-ede Spain.
Carlos ni lootọọ ni Messi ati Ronaldo n tii fi bọọlu dara, fun bi ọdun mẹẹdogun bayii, o ni Ronaldo Delima si ni baba wọn.
Carlos to jẹ akẹgbẹ rẹ ni Real Madrid ati Brazil jẹri wi pe o nira fawọn ẹlẹsẹ ayo lati gba bọọlu sawọn nigba naa ju akoko yii lọ nitori iyatọ ti ba ofin ere bọọlu nisin yii.