You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ ilẹ̀ Kenya gbé ‘búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín’ mì nígbà tó ǹ fọyín
Ọpọ awọn eeyan lo n ranti ọjọ lori awọn iṣẹlẹ apanilẹrin to ti ṣẹlẹ si wọn sẹyin.
Okunrin kan to ti gbe burọọṣi ifọyin me sẹyin ni orilẹ-ede Kenya naa n ranti bi o ṣe nilo iṣẹ abẹ nigba naa.
Orisirisi nkan ni awọn ọmọde ati ọdọ koda agbalagba maa n jẹ nigba miran ti wọn ko si mọ bi o ṣe lewu to.
Kini o ti ṣẹlẹ tẹlẹ?
Bo ti lẹ jẹ wipe o ya eniyan lẹnu julọ, awọn dokita lorilẹ-ede Kenya ti yọ burọọsi ifọyin kuro ni ikun arakunrin kan to gbe e mi.
Arakunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ, David Charo sọ wi pe oun ṣeeṣi gbe burọọsi ifọyin naa mi nigba t'oun fọ ẹyin rẹ.
Arakunrin naa ti lọ si ile iwosan bii marun un ki o to di wi pe o ri ile iwosan ti yoo ran lọwọ lati yọ ohun eelo ifoyin naa kuro ninu rẹ, lẹyin ti iwadii fihan pe lootọ ni burọọsi naa wa ninu rẹ.
Ile iṣẹ iroyin lorilẹ-ede naa pin aworan burọọsi naa lẹyin ti awọn dokita ṣe iṣẹ abẹ to yọ ohun ifọyin ọhun kuro ninu rẹ.
Awọn eniyan lori ikanni ibaraẹnisọrọ lori opo Twitter fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa.