Sergio Aguero: Ẹ̀rù n ba àwọn agbabọọlu láti padà sí ìdíje Premier League tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ padà

Atamatase fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester City, Sergio Aguero ti sọ pe ẹru a ti pada sori papa n ba awọn agbabọọlu pẹlu bi aarun coronavirus ṣe n tankalẹ.Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ni ireti wa pe idije Premier League yoo tẹsiwaju, eyi to tumọ si pe awọn agbabọọlu gbọdọ pada si papa igbaradi lọjọ kejidinlogun, oṣu Karun. Awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ṣe koko yoo si ṣe ipade lọjọ Ẹti lati jiroro lori ọna ti wọn yoo gbe e gba.Aguero sọ pe" ẹru n ba pupọ ninu awọn agbabọọlu nitori pe wọn ni ọmọ ati ẹbí."

Lasiko to n ba ileesẹ amohunmaworan El Chiringhito sọrọ, ọmọ orilẹ-ede Argentina ọhun sọ pe: "Ẹru n ba mi, sugbọn emi ati ọrẹbinrin mi lajọ wa nibi, mi o si ni i ifarakanra pẹlu awọn eeyan miran. Inu ile mi ni mo wa, ọrẹbinrin mi si nikan ni mo le ko o ran."Wọn sọ pe awọn kan wà to ni Covid-19, sugbọn ti ko fi àpẹẹrẹ kankan han, tí wọn si le ko ran elomiran. Nitori naa ni mo ṣe duro sile, tori boya mo ni aarun naa ti mi o mọ."Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta ni wọn so idije Premier League rọ nitori coronavirus, sugbọn gbogbo awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu lo ṣetan lati gba ifẹsẹwọnsẹ mejilelaadọrun to ṣẹku.Wọn yoo si gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ naa lai si eero iworan. Bakanna ni wọn n gbeero lati fi awọn idije kan han lori amohunmaworan lọfẹ.

Ẹwẹ, àwọn oludari eto ilera yoo sepade lọjọ Ẹti lati jiroro lori ilana ti wọn yoo gbe nkan gba.BBC Sport ri i gbọ wi pe wọn yoo ṣe ayẹwo aarun coronavirus fun awọn agbabọọlu lẹẹmeji lọsẹ, ti igbaradi ba bẹrẹ saaju ki ofin konile o gbele to kasẹ nilẹ.

Bakan naa ni awọn agbabọọlu gbọdọ maa lo í ọmú ni gbogbo igba ti wọn ba wa ni papa. Wọn ko si gbọdọ si oúnjẹ jíjẹ tabi iwẹ ni ibudo naa.Awọn eleto ilera to ṣe koko nìkan si ni anfaani yoo wa fun lati wọle, wọn si gbọdọ wọ aṣọ idaabo bo.

Gbogbo ipade ati ijiroro gbọdọ maa waye lori ayelujara. Sugbọn sa, atamatase ẹgbẹ́ agbabọọlu Brighton, Glenn Murray sọ pe awọn ilana kan ti wọn la kalẹ le ma a ṣíṣẹ, paapa ibomu lilo nitori pe "awọn agbabọọlu yoo ma a yọ sọnu lasiko ti wọn ba n gba bọọlu".

O sọ pe "idi ti awọn eeyan fi fẹ́ ẹ pada sori papa ye mi, sugbọn wọn gbọdọ ṣe e ni ọna to mu ọgbọ́n dani, ati ni asiko to tọ́, ni ọna ti aabo yoo fi wa fun gbogbo eniyan, nitori pe kaakiri agbaye ni awọn agbabọọlu yoo ti wa, ko si si ẹni to mọ àwọn to ni i"."Mo ni awọn ọmọ nilẹ, mi o si ni i fẹ́ fi wọn sinu ewu. Awọn agbabọọlu kan ni ọmọ tuntun nile, bẹ ẹ làwọn kan si n gbé pẹlu arugbo wọn. Nitori naa, igbesẹ ti ko bojumu ni bi wọn ṣe sọ pe ki idije o bẹrẹ pada. Ẹgbẹ́ agbabọọlu Arsenal, Brighton ati West Ham ti si ibudo igbaradi wọn silẹ fun awọn agbabọọlu lati ma a da ṣe igbaradi.