Premier League: Liverpool fẹ́ gbafe yìí ṣá! Premier League yóò bẹ̀rẹ̀ padà lóṣù kẹfà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbogbo eto ti to bayii lati bẹrẹ idije Premier League lọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun yii lẹyin to ti wa nin idaduro nitori ajakalẹ aarun coronavirus.

Ohun ti awọn alaṣẹ idije naa n gbero ni lati gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to ku tan laarin ọsẹ mẹfa ni kete ti idije naa ba ti bẹrẹ pada.

Inu ọpọlọ awọn ololufẹ idije Premier lo dun pe idije naa yoo pada laipẹ ọjọ.

Ijọba ilẹ Gẹẹsi rọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ogun to wa ninu idije naa lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku lawọn papa iṣere mii yatọ si ti wọn.

Ṣugbọn awọn ikọ agbabọọlu kọ jalẹ, wọn ni o wu awọn lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku nile awọn.

Liverpool lo wa loke tente tabili EPL, nigba ti ifẹsẹwọnsẹ to ku si jẹ mọkanla.