You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oronsaye reports: Kí ló wà nínú àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ Oronsaye gan an tó ń kó ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ láyà sókè?
Laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọ lawọn ile ẹkọ fasiti nilẹ wa, (NASU) ati awọn ẹgbẹ miran to so mọ figbe ta pe, ijọba apapọ ti n gbe igbesẹ lati ṣe amulo abọ iwadii igbimọ Stephen Orosanye nipa isẹ ọba.
Bẹẹ ba gbagbe, ijọba ana ti aarẹ Goodluck Jonathan dari, lo gbe igbimọ naa kalẹ lati ṣe atunto ẹka isẹ ọba ni Naijiria, tí abọ igbimọ naa si foju han sita ni oṣu kẹrin ọdun 2012, eyi ti ìjọba Buhari ti tẹwọ gba bayii.
Amọ ẹgbẹ NASU ni ìjọba fẹ lo abọ iwadii Orosanye naa lasiko yii ti ajakalẹ arun Coronavirus ti mu ki ọrọ aje Naijiria dagun, lati da awọn ẹka ileeṣẹ ijọba kan papọ lọna ati gba isẹ lọwọ awon oṣiṣẹ ọba.
Idi ree ti BBC Yoruba fi ṣe agbeyẹwo awọn koko to wa ninu abọ iwadii Orosanye naa, oloju ewe ẹgbẹrin, eyi to n ko ibẹru si aya awọn oṣiṣẹ.
Koko to wa ninu abọ iwadii igbimọ Orosanye:
- Ko si ofin kankan to ti idasilẹ aadọta ninu awọn ileeṣẹ lajọ-lajọ kan to jẹ tijọba lẹyin, ó si yẹ ki wọn pa rẹ
- Ipenija ati iṣoro nla wa ninu sise akoso awọn ileesẹ ijọba, nitori bi wọn ṣe ko awọn ẹka kan ati lajọ-lajọ kuro labẹ wọn, ti isẹ tawọn ẹka naa si n ṣe ti yọ silẹ.
- Iṣẹ awọn oṣiṣẹ ọba to yẹ ko waye ni ọna kan ti n waye lọna pupọ, nitori bi wọn ṣe n da awọn ẹka ileesẹ ati lajọ-lajọ ti ojuse wọn jọra silẹ, eyi ti ko tun jẹ ki iṣẹ awọn oṣiṣẹ ọba pegede si.
- Awọn aba to jọ mọ gbesẹ lati da awọn ileesẹ ti isẹ wọn jọra papọ. Fun apẹẹrẹ, dida ileesẹ ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, papọ mọ ileesẹ Ọlọpaa.
- Awọn ileesẹ miran ti isẹ wọn tun jọ ara wọn, ti igbimọ Orosanye dabaa pe ki wọn papọ ni ajọ Fiscal Responsibility Commission, ajọ Paṣẹrẹ ti wọn pe ni National Poverty Eradication Programme, Utilities Service Commission, National Economic Intelligence Committee, ajọ to n wa idẹrun ọmọlẹyin Kristi ni ilẹ mimọ, ti wọn n pe ni Nigerian Christian Pilgrim Commission ati ajọ alalaji ti National Hajj Commission.
- Awọn ileesẹ ijọba to to mejile lọgọrun-un ni igbimọ Orosanye dabaa pe ki ijọba parẹ ninu ojilelẹẹdẹgbẹta, 541, awọn ileesẹ ti ijọba ni.
- Ki ijọba yọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ to jẹ isẹ aayan laayo, professional bodies, kuro ninu isuna ijọba.
Face mask: Owó ìtanràn N40,000 nítorípé mí ò wọ ìbòmú- Vincent
Adajọ Majistireti kan ni ilu Ekiti ti dajọ pe ki arakunrin kan to kọ lati wọ ibomu lasiko Coronavirus yi san owo ijiya ẹgbẹrun lọna ogoji Naira.
Owo Ijiya yi pẹlu pe yoo sisẹ sin ilu ni adajọ Julius Ajibare ni ko maa jẹ ijiya ati ẹkọ fun Ikechukwu Vincent to tapa si ofin to pọn ni dandan ki awọn eeyan wọ ibomu ti wọn ba jade sita nipinlẹ Ekiti.
Majistireti Oluwasanmi lasiko to n gbe idajọ rẹ kalẹ sọ pe iwa naa le dẹmi awọn eeyan legbodo nitori ewu to wa nita pẹlu Coronavirus.
O ni: ''Nitorinaa, iwa ọdaran gbaa ni pe ki eeyan mọọmọ tapa si ofin yi''
Ọjọ mẹta ni Vincent yoo fi sisẹ sin lu.
Ninu ọrọ rẹ, Vincent ni ijiya ti ile ẹjọ gbe kalẹ yi jẹ ohun to kan oun laya.
O ni adajọ naa fẹ mọọmọ fi iya jẹ oun ni nitori ijiya yi ju ẹsẹ ti oun sẹ lọ.
Sugbọn sa, olupẹjọ, Femi Onipede sọ pe ijọba ko sẹsẹ maa kede lori redio ati ọna ibaraẹnisọrọ miran saaju asiko lori pataki wiwọ ibomu yi.
O nitori naa, ko le wa maa faraya lori idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ nitori ile ẹjọ ni gbogbo agbara lati gbe idajọ to ba wu u kalẹ fẹni tapa si ofin.
'Atunse ofin lo le dẹkun jẹgudujẹra'
Niyi Akintọla: Atunse ofin lo le dẹkun jẹgudujẹra
Niyi Akintọla ni ti atunse ko ba ba ofin Naijiria, iwọnba ni ijiya awọn oni jẹgudu-jẹra yoo maa jẹ.
Amofin agba kan lorilẹẹde Naijiria ti pe fun agbeyẹwo ofin gẹgẹ bi ọna lati dẹkun iwa jẹgudujẹra lawujọ.
Amofin Niyi Akintola woye ọrọ naa nigba to nwoye lori bi ile ẹjo kan nilu Abuja se yi idajo pada lori ẹsun ikowoje ti wọn fi kan osise kan nileesẹ to nsakoso owo ifẹyinti awọn ọlọpaa kan, ogbẹni Yakubu Yusuf.
Saaju ni adajo ile ejo giga kan labuja ti dajo ewọn ọdun meji tabi owo itanran ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa nair (N750,000) fun-un, lori ẹsun pe o lu biliọnu mẹrinlelogun naira owo ifẹyinti ọlọpaa ni ponpo.
Ninu idajọ tuntun naa, adajọ ile ẹjo kotẹmilorun, adajo Abdul Aboki, ni ki Yusuf lo fi ẹwon ọdun mẹfa gbara, ko si da owo biliọnu mejilelogun pada.
Akintola ni, kii se ẹbi adajọ pe ijiya lọpọ igba lori ẹsun kikowo je, ki farajọ bi ẹse ti se wuwo si.
'ilana ofin nipa ẹjọ ti wọn ba ti gbe wọn lo si iwaju adajọ ni wọn gbodo tele. Bi iwe ofin ba ti se la ijiya kale ni adajọ yoo se tele. Ko le m'ofin tire wa yato si eyi to wa ninu ofin''
Akintola ni asiko ti to bayi lati wa wọrọko fi sada lori ofin ile Naijiria eyi ti ''ọpọ ninu wọn ko ba ilana ofin ode oni mu''
Idajo pataki re fun awọn osisefeyinti
Ajo to ngbogun ti iwa ibaje lorileede Naijiria, EFCC kan sara si idajọ tuntun naa loju opo twita re
Awọn ọmọ Naijiria naa si f'ero ọkan wọn han
O ti to ọdun marun ti wọn ti wa lori ẹjo ọgbẹni Yakubu Yusuf.
Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:
Biliọnu mẹtalelọgbọn ni iye owo ti wọn ni o koje.
Lẹyin ti o jẹwo pe oun ji biliọnu meji, ile ẹjo giga dajọ ẹwọn ọdun meji fun tabi owo itanran ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa naira.
Ọrọ naa bi ọpọ eeyan ninu to fi mo ajọ to nse akoso ẹka idajọ to ni ki adajọ to da ẹjo naa lo rọọkun nile fun ọdun kan lori idajọ to da.