You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Messis vs Ronaldo: Jurgen Klopp ní àràmọ̀ndà agbábọ́ọ̀lù tó ń jẹ Messi, ó ju Ronaldo lọ lórí pápá
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp naa ti da si arayinjiyan "ta lo dara ju" laarin Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo.Ko tii si opin si ariyanjuyan yii lẹyin tawọn mejeeji ti tayọ ju awọn akẹgbẹ wọn lagbaaye lọ fun bi ọdun mẹwaa sẹyin bayii.Ronaldo ati Messi jọ dabira ninu idije La Liga nibi ti wọn ti jọ gba ami ẹyẹ loriṣiiriṣii fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn, Real Madrid ati Barcelona ki Ronaldo to darapọ ikọ Juventus.
- Ṣé ẹ lè kí Liverpool kú oríire báyìí? Premier League yóò bẹ̀rẹ̀ padà lóṣù kẹfà
- NFF fi #30,000 kún #10,000 owó ìrànwọ́ oṣooṣù fún ìyá Rashidi Yekini àti Samuel Okwaraji
- Mo kábàámọ̀ pé n kò kàwé, kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà - Sanyeri
- Aláàfin gbé àṣẹ kalẹ̀ láti dènà àtúnṣẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ 'Soka'nílùú Ọ̀yọ̀
- Nínú ìṣèjọba yìí, Èmi àti Ààrẹ Buhari lọlọ́rọ̀, kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà-Ibrahim Gambari, olórí òṣìṣẹ́ lọ́fíìsì ààrẹ
- Àwọn alárùn coronavirus ṣe ìwọ́de ní Gombe, wọ́n ní ìjọba n febi pa wọ́nAmọ, Klopp ṣalaye pe lootọọ ni Ronaldo jẹ agbabọọlu to lamilaaka, o ga, o le fo, o le sare, gbogbo amuyẹ agbaọjẹ agbabọọlu pata lo ni.Klopp ni laisi ani-ani, ara ọtọ ni Messi! O kere nilẹ ju Ronaldo lọ, amọ o n fi bọọlu dabira nla lori papa, koda pẹlu irọrun lo maa fi n ṣe ohun gbogbo.Ṣugbọn akọnimọọgba Liverpool ni Messi ati Ronaldo ti ṣe nnkan manigbagbe ninu ere bọọlu, o ni laelae lawọn eeyan yoo maa ṣe iranti wọn lọjọ iwaju.Messi ti gba ami ẹyẹ Ballon D'or nigba mẹfa ọtọtọ, nigba ti Ronaldo naa ti gbami ẹyẹ ọhun nigba marun un.