You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Odion Ighalo: Ó di 2021 kí Ighalo tó fi Manchester United
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti sọ idi ti wọn fi ṣe adehun tuntun pẹlu ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo eyi ti yoo mu un di oṣu ọdun 2021 pẹlu ikọ naa.
Lori opo ayelujara ikansiraẹni Twitter ni Man U ti fidi ọrọ naa mulẹ lọjọ Aje.
Lasiko ti ọja rira agbabọọlu ṣi silẹ ninu oṣu kinni ọdun 2020 ni Ighalo darapọ mọ Manchester United lati ikọ agbabọọlu China, Shanghai Shenhua.
- Ó ṣeéṣe kí ilé ìjọsìn, mọ́sálásí àti ọkọ òfurufú ṣí, Ẹ wo àwọn ìlànà tuntun tí ìjọba là sílẹ̀
- Awọn àkẹkọ̀ọ́ Uniben wọ́de ìfẹ̀hónú hàn nítórí akẹgbẹ́ wọ́n tí wọ́n fipa bálòpọ̀
- Gómínà Kogi pàṣẹ kóníléógbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Kogi
- Ọwọ́ bàtá Auxiliary tó ń ró ní àrójù, leè ya láìpẹ́ - Ìjọba Oyo dúnkookò
Ighalo ti gba goolu mẹrin sawọn lẹẹmẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to lanfaani lati ṣoju Man U ninu rẹ ki o to di wi pe wọn so ere bọọlu rọ nilẹ Gẹẹsi nitori ajakalẹ aarun coronavirus.
Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Man U ti sọ loju opo Twitter pe ohun to jẹ kawọn ṣe adehun tuntun pẹlu Ighalo ni pe o farajin ṣiṣẹ atawọn goolu to ti gba sawọn.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Ighalo gan an fun ra rẹ ṣalaye laipẹ yii bi o ti fi owo ounjẹ ọsan rẹ lọ wo ere bọọlu Man U.
O ni oun atawọn ẹgbọn ati aburo oun maa n ya owo sọtọ ninu owo ounjẹ lati le lanfaani wo Manchester United.
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Man U, Ole Gunnar Solskjaer sọ pe oun fẹ ki Ighalo gba ife ẹyẹ pẹlu Man U ko to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ.