Joy Nunei dá awuyewuye silẹ̀, Buhari pinnu láti túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí ìdàgbàsókè Niger Delta

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe gbogbo ohun ti yoo gba ni oun fun lati tuṣu de isalẹ ikoko idi ti ko fi si idagbasoke ni agbegbe Niger Delta lẹyin ẹgbẹlẹgbẹ owo ti ijọba apapọ n rọ s'agbegbe ọhun lọdọdun.

Buhari lo sọ ọrọ naa loju opo Twitter rẹ nibi to ti sọ pe afojusun ijọba oun ni lati mu ki idagbasoke de ba agbegbe naa.

O ni "Mo ti paṣẹ fun awọn aṣoju-sofin ati agbofinro lati fọwọ-sowọpọ ki wọn lee mọ ibi ti owo ti ijọba n la kalẹ fun agbegbe naa n wọlẹ si."

Aarẹ tẹsiwaju pe ki gbogbo ileeṣẹ ati ajọ to n ṣewadii ajọ NDDC jara mọṣẹ, ki wọn si bu oun gbọ lori ibi ti wọn ba baṣẹ de.

Buhari pari ọrọ rẹ pe ijọba oun ko ni bojuwẹyin ninu afojusun rẹ lati ri pe ajọ NDDC atawọn ileeṣe ijooba apapọ miran kun oju oṣuwọn lẹnu iṣẹ wọn, ati pe ki gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe nibẹ han si gbogbo ọmọ Naijiria.

Nnkan bi ọsẹ diẹ sẹyin ni awuyewuye ṣiṣe owo baṣubaṣu jẹyọ ni ajọ ọhun, koda wọn fi ọwọ osi juwe ile fun adari ajọ naa tẹlẹ, Joy Nunieh.

Ṣaaju ni igbimọ to n ri si ọrọ NDDC nile aṣoju-sofin ti kọkọ gbiyanju lati tu iṣu de isalẹ ikoko nipa ẹsun iṣowo baṣubaṣu ti wọn fi kan ajọ ọhun ni ibẹrẹ ọdun 2020.

Ṣugbọn iwadii ọhun dojuru lẹyin ti awọn ti wọn fiwe pe lati NDDC jade kuro niwaju igbimọ naa pẹlu ibinu.

Igbesẹ naa si ti mu ki igbimọ ọhun paṣe pe ki awọn agbofinro fi panpẹ ofin mu awọn adari ajọ ọhun, ki wọn lee wa sọ tẹnu wọn bi ọrọ owo naa ṣe jẹ.

Sinimá oríta nílé aṣojú-sòfin, NDDC bínú jáde ní ibùdó ìwádìí

Awọn adari ajọ Niger Delta Development Commission, NDDC ti jade kuro ni gbọngan ti ile igbimọ aṣofin kekere ti n ṣe iwadii owo to le ni biliọnu mọkanlelọgọrin naira.

Ṣaaju ni igbimọ to n ri si ọrọ NDDC nile naa ti kọkọ gbiyanju lati tu iṣu de isalẹ ikoko nipa ẹsun iṣowo baṣubaṣu ti wọn fi kan ajọ ọhun laarin oṣu Kinni si oṣu Keje ọdun 2020.

Alakoso fidihẹ fun ajọ naa, Kemebrandikumo Pondei, to ko awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ lọ sibi iwadii ọhun sọ pe, alaga igbimọ oluwadi naa, Olubunmi Tunji-Ojo ko yẹ lẹni ti yoo dari iwadii naa nitori wọn ti fi ẹsun aṣemaṣe nipa ajọ ọhun kan oun naa ri.

Ṣugbọn pupọ ninu awọn ọmọ igbimọ to n ṣe iwadii owo ọhun fesi pe, Pondei ko lẹtọ lati pa iru aṣẹ bẹẹ niwaju igbimọ ọhun.

Wọn ni ko kọwe si ileeṣẹ ọlọpaa, tabi ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra atawọn ajọ miran to n gbogun ti iwa ibajẹ, to ba ni ẹsun kankan lati fi kan Olubunmi Tunji-Ojo.

Bii sinima orita lo ri lẹyin ti awọn aṣoju ajọ NDDC naa jade kuro niwaju igbimọ iwadii ọhun, ti wọn si fi awọn oluwadii silẹ lori ijoko.

Igbesẹ yii ko dun mọ igbimọ oluwadii naa ninu, eyi si ti mu ki wọn paṣe pe ki awọn agbofinro fi panpẹ ofin mu wọn, ki wọn lee wa sọ tẹnu wọn fun awọn ọmọ Naijiria lori bi ọrọ owo naa ṣe jẹ.

'Àrùn Coronavirus ló pá adarí ètò ìṣúná Àjọ NDDC '

Ajọ Niger Delta Development Commission ti kede pe arun Coronavirus lo pa adari eto isuna, Ibanga Etang.

Owúrò Ọjọ́bọ̀, Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Karun un ní àdarí ẹ̀ka ètò ìṣúná yóò jáde láyé.

Ajọ naa ni awọn ẹbi lo fun wọn laṣẹ lati kede iku Ibang lẹyin ti ayẹwọ fihan pe o ni arun Coronavirus.

Bakan naa ni ileeṣẹ eto ilẹra ni ijọba ipinlẹ Rivers ti kọ iwe si Ajọ NDDC lati si ajọ loju eegun iku to Etang.

Nibayii, Ajọ naa ti wa paṣẹ ki awọn adari ni ajọ naa wa ni iyasọtọ bẹrẹ lati Ọjọ Iṣẹgun.

Bakan naa ni Ajọ NDDC ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ si ni wa gbogbo awọn to ti farakan adari eto isuna, Ibanga Etang to di oloogbe naa.

Wo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ 20 tí àrùn coronavirus pọ̀ sí jùlọ ní Nàìjíríà

Ni ọjọ aje ni igbimọ apapọ lori gbigbogun ti ajakalẹ arun coronavirus lorilẹede Naijiria, PTF jade pẹlu awsn ilana tuntun ti aarẹ buwọlu fun didena itankalẹ arun COVID-19.

Nibẹ ni wọn si ti ṣalaye wi pe awọn ti ṣe awari awọn ijọba ibilẹ ti arun Coronavirus ti fidimulẹ julọ lorilẹede Naijiria.

Boss Mustapha akọwe ijọba apapọ to tun jẹ alaga igbimọ naa ṣalaye pe awọn ijọba ibilẹ bii ogun naa ni wọn ko ida bii ọgọta ninu ọgọrun iye arun coronavirus lorilẹede Naijiria.

Awọn ijọ ibilẹ naa niwọnyii:

Ìjọba àpapọ̀ kò tíì fi ìlànà ṣíṣí iléèjọ́sìn ránṣẹ́ sí wa-Ẹgbẹ́ Mùsùlùmí tó ga jù ní Nàìjíríà, NSCIA

Ajọ Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs ti sọ wi pe awọn n rọ ijọba lati ri pe awọn n fin awọn ile ijọsin kaakiri ni ojoojumọ nitori awọn ile ijọsin ko ni owo lati se e.

Eyi ko ṣẹyin aṣẹ aarẹ Buhari pe ki awọn ile ijọsin pada bẹrẹ si ni si fun awọn eniyan lọna ati jẹ ki ofin konile-o-gbele rọle si ni Naijiria.

Akọwe Ajọ Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede lasiko to n ba BBC sọrọ ni awọn ko ni owo lati ma a fin ileejọsin ni ojoojumọ nitori awọn kii gba owo ni ile ijọsin, wọn kan n lọ sin Olorun ni.

Bẹẹ ni Oloyede ni awọn kii gba iranwọ lati ile okeere tabi abẹle lati fi se akoso awọn mọsalasi kaakiri orilẹede Naijiria nitori naa ni awọn ṣe n rọ ijọba lati ran awn lọwọ pẹlu oogun apakokoro.

O fikun pe owo ti awọn eniyan ba fi ta wọn lọrẹ ni awọn fi n ṣakoso mọsalasi kaakiri Naijiria.

Ṣe ofin ijinasiraẹni ko tako ẹsin Musulumi?

Akọwe Ajọ Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ti ni ofin ijinasiraẹni lasiko arun Coronavirus ko tako ẹsin Musulumi.

Ọjọgbọn Oloyede ni ẹsin Islam fagbaye gba yiyago fun araẹni ti o ba ma a mu inira dani.

O ni Islam jẹ ẹsin ti ko fun ẹnikẹni ni inira ju ohun ti agbara rẹ gbe lọ, ko da wọn le e ṣẹ ẹsin ninu ile, ti wọn ba ṣe aisan, wọn le e dubulẹ kirun bo ba ṣe rọ wọn lọrun si.

Ṣé ìjọba àpapọ̀ tí ṣí àwọn ìléèwé àti ilé ìjọsìn padà bí?

Ijọba apapọ ni titpa lawọn ileewe yoo ṣi wa bayii nitori bi iye awọn to n ni arun naa ṣe n fojojumọ gogo sii lorilẹede Naijiria.

Igbimọ amuṣẹya ti ijsba apapọ gbe kalẹ lori arun coronavirus lo sọ bẹẹ lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlawọn oniroyin.

Igbesẹ naa si wa lara awọn igbesẹ to wa nilẹ eyi ti igbims naa ni, pẹlu ifọwọsi aarẹ muhammadu Buhari, ṣi n tẹsiwaju.

Nigeria Lockdown Updates: Ẹ wo àwọn ìlànà tuntun tí ìjọba là sílẹ̀, ó ṣeéṣe kí ilé ìjọsìn, mọ́sálásí àti ọkọ òfurufú ṣí

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni àwọn ti wọ ipele kéji fún dídẹ ọkùn ìgbéle ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà báyìí.

Alága ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lórí ààrùn coronavirus lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tún jẹ́ akọwé ìjọba àpapọ̀ Boss Mustapha ló kéde èyí lásìkò tó n jábọ ibi abáṣẹ́dé lorí Covid-19 lọ́sàn òní nílùú Abuja.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ipele kejì yìí yóò wà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin láti ọjọ́ kejì oṣù kẹfa sí ọjọ́ kọkàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà, ọdún 2020.

Mustapha ni óṣeéṣe kí àwọn ilé ìjọsìn ṣí bótilẹ̀ jẹ́ pé kò ni sí ìpíjọpọ̀ to ju ogún èèyàn lọ níbikíbi to ba yàtọ̀ si ibi iṣk àti ilé ìjọsìn.

Àwọn ǹkan míràn ti yóò tún wáyé lásìkò ipele kejì yìí rèé.

  • Ijọba ti kéde pé àṣẹ kóníléógbélé tó wà ni aagoo mẹ́fà ìdájí sí aago mẹ́jọ alẹ́ tẹ́lẹ̀ yóò sún si aagoo mẹ́rin ìdájí sí aago mẹ́wàá alẹ́
  • Ó ṣeéṣe kí ọkọ̀ òfurufú alábẹ́lé ó bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kọ́kànlélógún oṣù kẹfà ọdún 2020, gẹ́gẹ́ bí a ọ̀e sọfún fún àwọn ẹka náà láti ṣètò ìlànà ti àwọn yóò maa tèlé.
  • Kóníléógbélé kòkan àwọn òṣìṣé tó n ṣiṣẹ́ covid-19
  • Kò tí sí ìrìnàjò láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn
  • Kí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ bánkì padà sẹnu iṣẹ́, kí wọ́n sì maa lo àsìkò wọ́n pé, bákan náà ni àwọn ilé iṣẹ́ aládani lé padà sí bí wan ṣe n ṣe tẹ́lẹ̀, níwọ́n ìgbà ti iṣẹ́ wọ́n yóò ba ti maa parí kí àsìkò kóníléógbélé tó bẹ̀rẹ̀.
  • Gbogbo ilé ẹkọ́ yóò sì wà ní títì pa, nígbà ti ilé iṣẹ́ tó n rí sí ètò ẹ̀kọ́ yóò máa ṣetò pẹ̀lú àwọn ilé iwé lórí àwọn ìlànà ti wọ́n lè tèlé nítori àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ jáde ti J.S.S 3 àti S.S.S 3 bí wọ́n yóò se kọ ìdáwò wọ́n.
  • Ilé ìjọsìn àti mọ́sálásí yóò máa tẹ̀lé ìlànà ti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kàn bá là sílẹ̀ fún wọ́n.
  • Àwọn ènìyàn le padà sí bí wan ṣe n ṣe tẹ́lẹ̀ bí eré ìdáraya, tí ìdá márùndílọ́gọ́rin èèyàn sì ni yóò máa péjú sí ibiṣẹ́ kí àlàfo to péye baa lè wà.
  • Kò sí ààye fún ènìyàn to bá ti lé ni ogún ènìyàn lẹyìn ibiṣẹ́
  • Kò ní sí kóníléógbéle òní láyípo ní ìpínlẹ̀ Kano mọ́, sùgbọ́n ìpele tí àwọn ìpínlẹ̀ tókù fi sill ni wọ́n yóóò wà báyìí, eyí túmọ̀ sí pé,aago mẹ́fà ààrọ sí aago mẹ́jọ alẹ́ ni wọ́n yóò maa fi jáde.
  • Awọn ilé oúnjẹ kò gbọdọ gbà kí àwọn ènìyàn jòkó jẹ́un, kí wọ́n ràá ki wọ́n sì máa lọ ni.

Ní báyìí orílẹ̀-èdeè Nàìjíríà ti ní èèyàn tó lé ni ẹgbẹ̀run mẹ́wàá tó ti ni ààrùn Covid-19 tí èǹiyàn to lé ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ti móríbọ́ ti àwọn to lé ní igba sì ti báa lọ

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ kí Ààrẹ Buhari ṣí wọn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin kónílé -ó-gbélé

President Buhari speech today: Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Naijiria fẹ́ kí Ààrẹ Buhari ṣí wọn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin kónílé -ó-gbélé

Nibayii, a n reti ohun ti aarẹ Buhari yoo kede lọni lẹyin ti Ajọ amuṣẹya aarẹ lori arun Coronavirus, PTF fi lede wi pe awọn ti jiyin fun aarẹ lori bo ṣẹ n lọ ni Naijiria ati amọran fun aarẹ Buhari boya ki ofin konile o gbele tẹsiwaju abi ko dopin.

Ọjọ Ajẹ, ọsẹ yii lo pe ọṣẹ kẹrin ti irọlẹ ofin konile o gbele bẹrẹ ni Naijiria, amọ ofin naa si de irinna lati ipinlẹ kan si omiran.

Amọ, ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria to fi ẹrọ wọn lede loju opo BBC Yoruba lori Facebook ti kesi aare lati tu awọn silẹ lọwọ ofin konile-o-gbele ti yoo pari loni.

Awọn to fi ero wọn han naa sọ wi pe awọn fẹ ki awọn nkan pada si bi o ti wa tẹlẹ ki arun Coronavirus to bẹ silẹ ni Niajiria.

Lara awọn to fi ero wọn lede ohun sọ pe iya ati iṣẹ ti poju lawujọ lasiko arun Coronavirus yii, nitori naa ki ijọba fi wọn silẹ lati wa ounjẹ ojo wọn.

Awọn miran ti lẹ sọ wi pe ki aarẹ jẹ ki ileewe ṣi, ki awọn olukọ le pada si ẹnu iṣẹ, ki awọn ti wọn ti kuna iṣẹ wọn nitori arun Coronavirus naa le ri iṣẹ.

Amọ awọn to fẹ ki ofin konile o gbele o tẹsiwaju ko po to awọn to fẹ ki ofin naa di ohun ana.

Awọn kan ti lẹ sọ pe ko si eleyii to kan awọn, nkan to ba wu aarẹ Buhari nitori awọn ko ni igbagbọ ninu rẹ mọ.

Amọ loju ẹrọ ikansiraẹni Twitter, awọn elomiran n bere idi ti ijọba ṣe jẹki ofin konile-o-gbele rọlẹ nigba ti iye awọn to ti ni arun Coronavirus n peleke si ni Naijiria lojojumọ.