Lagos City Marathon: Ipò wo ni Gómìnà Sanwo-Olu gbà?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọmọ orilẹede Kenya, David Barmasai lo gba ami ẹyẹ ipo kinni ninu ere eje-gigun ti ilu Eko ti ọdun 2020.

Barmasai pari ere to le ni kilomita mejilelogoji laarin wakati meji ati iṣẹju mẹwaa.

Ẹbun owo to le ni miliọnu mejidinlogun naira ni Barmasai yoo mu re 'le fun ipo kinni to gba ninu ere ọhun.

Ọna ara ọtọ ni Barmasai ọmọ ilẹ Kenya gba jawe olubori ninu ere eje-gigun ọhun.

Ẹwẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu naa wa lara awọn to kopa ninu ere eje-gigun naa to waye niluu Eko lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun 2020.

Ninu isọri tawọn obinrin, Sharon Cherop ti oun naa jẹ ọmọ bibi ilẹ Kenya lo jawe olubori.

Iye owo kan naa ni ọkunrin ọkunrin ati obinrin to jawe olubori ninu ere eje-gigun naa jọ gba.

Eyi ni igba karun un ti ere eje-gigun yii yoo waye niluu Eko lẹyin ti alakọkọ iru rẹ waye lọdun 2016.