Odion Ighalo di ọmọ Naijria àkọ́kọ́ tí yóò gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ Manchester United

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti fi ọrọ lede pe Odion Ighalo ti darapọ mọ ikọ ọhun.

Eyii to tumọ si pe Ighalo ni ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo gba bọọlu fun ikọ Manchester United.

Ẹlẹsẹ ayo naa ni ikọ Man United n yalo lati ikọ rẹ tẹlẹ, Shanghai Greenland Shenhua to wa lorilẹ-ede China.

Akẹgbẹ rẹ tẹlẹ ninu ikọ Supper Eagles, Mikel Obi ni ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo tọwọ bọwe adehun pẹlu ikọ Man United, ṣugbọn ko gba bọọlu fun ikọ ọhun.

Igahlo to ti jẹ olofẹ ikọ Manchester United tẹlẹ ni awọn adari ikọ naa lero pe yoo kopa ribiribi ninu awọn idije saa yii to n lọ lọwọ.

Ṣaaju ni Igahlo ti n kopa ninu igbaradi pẹlu ikọ Shenshua fun saa tuntun, ṣugbọn saa naa ni idaduro nitori arun Corona to bẹ silẹ lorilẹ-ede China.

Gẹgẹ bi iroyin ti Sky Sports fi lede, ikọ Tottenham naa ti gbiynaju lati fa ọmọ ọgbọn ọdun ọhun mọra, ṣugbọn o kuna.

Ighalo bẹrẹ si ni di gbajumọ nidi iṣẹ bọọlu nigba to wa ni ẹgbẹ agbabọọlu Julius Berger ni Naijiria, ko to lọ si ikọ Udinese lorilẹ-ede Italy.

Ki Ighalo to kuro ni ikọ Supper Eagles, oun ni ẹni to gba bọọlu to pọju sinu awọn ninu idije AFCON to waye lọdun 2019 pẹlu bọọlu meje.

Ọpọlọpọ awọn ololufẹ Ighalo lo ya lẹnu pe "Red Devils" buwọlu igbesẹ Ighalo yii pẹlu bi Man U ṣe jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to gbajumọ gan lorilẹede Naijiria. Kete ti wn gbọ ni wn fọn sori ayelujara lati da si ọr naa.