Lagos Okada ban: Àwọn àkàndá ẹ̀dá ní àwìn làwọn gba kẹ̀kẹ́ táwọn fi ń jẹun

Ọrọ bi ijọba ipinlẹ Eko se fofin de ọkada ti n bọna miran yọ pẹlu oniruuru ifẹhonu han to n waye lati tako igbesẹ naa.

Ni aarọ ọjọ Aje lawọn akansa ẹda yabo ibujoko ijọba ipinlẹ Eko ni Alausa, ti wọn si n fẹhonu han sijọba lori bo se fofin de ilo ọkada ati kẹkẹ Maruwa lawọn agbegbe kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn akanda ẹda naa, ti wọn ni oniruuru ipenija ara, gbe ọpọ akọle lorisirisi lọwọ lati pe akiyesi ijọba si wahala ti wọn n koju latipasẹ fifi ofin de ọkada.

Lati ọpọ agbegbe nilu Eko si lawọn akanda ẹda naa, ti ọps wọn jẹ ẹya Hausa, ti wa se ifẹhonu han, koda, wọn tun lẹ awọn akọle wọn si ara kẹkẹ Maruwa ti wọn gbe wa se ẹhonu ọhun.

Nigba to n ba BBC sọrọ, ọkan lara awọn akanda ẹda naa, salaye pe awọn bọ sigboro lati ke gbajare tọ araalu wa, ki wọn lee mọ isoro tawọn akanda ẹda n koju nitori bijọba se fofin de ilo ọkada ati kẹkẹ Maruwa.

"Ijọba sọ fun wa pe a ko gbọdọ jade lọ se agbe loju popo, a gbọ si wọn lẹnu, a si pa owo wa pọ lati ra kẹkẹ Maruwa, ko lee maa mu owo wale fun wa.

A ra kẹkẹ mii ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira tabi ko din diẹ, koda omiran, a n sanwo rẹ diẹdiẹ ni."

"A n bọ ara wa, ẹbi wa ati awọn eeyan miran lawujọ, ta si tun n se iranwọ fawọn eeyan miran bii awọn ọlspa ta n gbe lọfẹ sinu kẹkẹ Maruwa wa.

Sugbọn ijọba lai ba wa sọ tẹlẹ, lọ fi ofin de lilo kẹkẹ Maruwa"

O fikun pe awọn akanda ẹda yii setan lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, amọ o wa n beere pe, se ijọba setan lati fun awọn lowo ranpẹ, kawọn fi joko sile tabi kawọn maa gba owo osu lọwọ wọn.

Sugbọn o ni ti eyi ko ba ri bẹẹ, awọn ko ni bọwọ fun ofin yii, ijọba Eko gbọdọ wọgile ofin yii, kawọn lee wulo fun ara awọn ati orilẹede wa.