Parties Deregulation: Olapade Agoro ní INEC kò fi tó àwọn léti pé ó fẹ́ wọ́gilé 74 ẹgbẹ́ òṣèlú

Lara awọn ẹgbẹ oṣelu ti ajọ eleto idibo Naijiria, INEC yọwọ wọn kuro lawo eto oṣelu Naijiria ti sọ pe, wọn ko faramọ igbẹsẹ ti INEC gbe.

Alaga ẹgbẹ oṣelu National Action Council, NAC , ọmọwe Olapade Agoro, sọ pe ohun to yẹ ki ajọ INEC ṣe ni ko kọkọ yọ ọwọ ara rẹ kuro lawo iṣakoso ẹgbẹ oṣelu Naijira, nitori ọwọ rẹ gan ko mọ.

O ni ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ajọ ọhun ma n gba riba lasiko idibo, ki wọn lee gbe are fun ẹlẹbi ninu esi idibo.

Ọjọgbọn ọhun ni o jẹ ohun to yanilẹnu pe, nigba idibo, ẹgbẹ PDP ati APC nikan lo ma n ko ibo to le ni ogoji miliọnu, nigba ti awọn ẹgbẹ yoku bii aadọta, maa ni ibo perete.

Agoro sọ fun BBC pe, "Nnkan ti INEC ṣe ko dara rara fun itẹsiwaju ijọba tiwantiwa ni Naijiria."

O ni ajọ INEC ko fi to ẹgbẹ oṣelu NAC leti pe, o ti yọ orukọ rẹ kuro lara awọn oṣelu titi di igba to kede fun awọn oniroyin.

O ṣalaye pe "Ṣe ori ẹrọ asọrọmagbesi lo yẹ ki a ti gbọ pe INEC ti yọ orukọ wa ni? Ko si ijọba tiwantiwa lorilẹ-ede yii rara."

Agoro pari ọrọ rẹ pe, o yẹ ki alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu kọwe fipo silẹ fun iwa aibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan to wu, lori igbeṣẹ naa.

Fatai Ibu Owo to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu National Conscience Party , NCP ipinlẹ Eko sọ fun BBC pe, igbeṣẹ ti INEC gbe ki n ṣe igbeṣẹ to ba ofin mu.

O ṣalaye pe, igbeṣẹ naa dabi ẹni to yin agbado ṣeyin awo ni, nitori ṣaaju ni awon ẹgbẹ bii mẹtalelọgbọn ti gbe INEC lọ ile ẹjọ lodi si igbeṣẹ naa.

O fikun pe ṣugbọn INEC gbe igbesẹ yii nigba ti ẹjọ naa ko tii pari.

Fatai sọ pe ko si ẹni to lagbara lati pa ẹgbẹ oṣelu kankan rẹ nitori ofin faaye gba ọmọ Naijiria lati ṣe ẹgbẹ oṣelu.

O ni "Ko yẹ ki a maa ni ara wa lara lorilẹ-ede yii, ni ṣe lo yẹ ki ijọba fun onikuluku laaye lati ṣe ẹgbẹ to wuu."