Tanker Fire: Eré àṣàpajúdé tí ọkọ́ epo náà sá ló fa ìjàmbá iná ọ̀hún

Ọkọ epo miran tun ti gbina ni ibudokọ Abule Ọsun lagbegbe bareke Ọjọọ nilu Eko.

Gẹgẹ bi ajọ to n dide si isẹlẹ pajawiri nilu Eko, LASEMA ti fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, ọkọ agbepo naa lo ko eroja disu, ti odiwọn rẹ to ẹgbẹrun mọkanla lita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkọ agbepo naa, ti wọn ko lee da nọmba rẹ mọ tori o ti jona, ni iwadi fihan pe lasiko ti ọkọ naa n sare asapajude, ni ile epo ẹyin rẹ ja, to si gbina.

Ko si ẹmi tabi dukia kankan to fara gba ninu isẹlẹ naa, ti ajọ LASEMA si ti n saayan lati bomi pa ina naa lai jẹ ki ọwọja ina ọhun ran si agbegbe miran.