You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn adigunjalè yabo bánkì méjì nípìnlẹ̀ Ondo, ènìyàn bi i mẹ́ta kú
O kere tan eniyan mẹta gbẹmi mi lasiko ti awọn adigunjale yabo ile ifowopamọsi meji ni ilu Ilẹ oluji ni ipinlẹ Ondo.
Ọsan Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye ni ijọba ibilẹ Ilẹ Oluji/Okeigbo ni ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Femi Joseph to ba BBC sọrọ sọ pe oun ko ti i le sọ bi iṣẹlẹ naa ṣẹ waye.
Joseph ni banki Polaris ati First Bank ni wọn ṣe ikọlu si, amọ o ni ilẹkun atiwọle si Polaris Bank nikan ni wọn ri bajẹ, ti wọn si ṣọṣẹ ni First Bank.
O fikun pe awọn ọlọpaa wa lara awọn to ku nibi iṣẹlẹ naa.
Awọn ti iroyin naa ṣe oju wọn ni ado oloro kekeeke ni awọn adigunjale naa lo lati fi wọ inu banki naa.