Samson Siasia: Ẹ rànmí ìrànwọ́ pẹ̀lú N100m láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn mi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles, Samson Siasia ti bẹ bẹ iranwo to to ọgọrun un miliọnu naira lati fi ṣe ẹjọ lori ẹsun riba ti ajọ FIFA fi kan an.

Loṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni ajọ FIFA fẹsun kan Siasia pe o gba lati tẹwọ gba riba lati ṣe eeru ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ kan to ti waye sẹyin.

Siasia ni oun ti gbiyanju agbara oun lati wa owo ti yoo fi ṣe ẹjọ naa nile ẹjọ to n ri si awuyewuye to ba jẹyọ nibi ere bọọlu afẹsẹgba lagbaaye.

Ṣugbọn awọ ko tii ka oju ilu nitori ọgọrun un miliọnu kii ṣe owo ọmọde owo.

Siasia tun ti wa kepe ijọba apapọ atawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ pẹlu owo ki oun le yọ orukọ oun ninu ẹsun jibiti ti wọn fi kan oun.

Ajọ FIFA fofin de Siasia pe ko gbọdọ ni ohun kankan ṣe mọ pẹlu ere bọọlu, amọ o ni oun ko mọwọ, bẹẹ ni oun ko mẹsẹ lori ọrọ naa.

Siasia to wa lara awọn agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ ilẹ Afirika lọdun 1994 lorilẹ-ede Tunisia, sọ pe lori ayelujara loun naa ti gbọ ẹsun ti ajọ FIFA fi kan oun gẹgẹ bi ọpọ ọmọ Naijiria naa ṣe rii.

Siasia ni: Mo kan ṣadeedee gba ipe lati ọdọ ọwọ aarẹ ajọ NFF to n dari ere bọọlu ni Naijiria ninu eyi to ti bi mi leere boya mo ti ri lẹta lati ọdọ FIFA,

O ni lẹyin naa loun ri lẹta ọhun ninu ẹrọ agbọrọkaye oun ṣugbọn Siasia sọ pe oun ko mọ nnkankan lori ẹsun ti wọn fi kan oun.

Yatọ si pe ajọ FIFA fofin de Siasia, ajọ naa tun ni ko san owo itanran bi miliọnu mejidinlogun naira.

Igbẹjọ naa yoo waye lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹta ọdun yii niluu Lausanne, lorilẹede Switzerland.