Tinubu: Buhari kò leè du ipò fún sáà kẹta láéláé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Aarẹ Muhammadu Buhari ati Asiwaju Bola Ahmed Tinubu sepade pọ nilu Abuja lọjọ Isẹgun.

Lẹyin ipade bonkẹlẹ to waye laarin awọn mejeeji, Tinubu sọ fun awọn ọmọ Naijiria pe asaaju Naijiria naa jẹ oniwa rere ati onigboya eniyan, ti ko si lee fẹ se saa kẹta lori aleefa laelae.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ Naijiria ti ori rẹ ba pe, to ba si ti ba aarẹ Muhammadu Buhari sisẹ ri yoo mọ pe kii se ẹni to lee ti ọwọ bọ ofin ilẹ wa Naijiria.

Awọn eeyan ti ko fẹ ko gbajumọ isẹ to n se lori ipo aarẹ, lo n fura kiri, ti wọn si n fi awọn ẹsun ti ko tọ kan Buhari, sugbọn emi ni mo ti n ja fun ifẹsẹmulẹ ijọba awa ara wa.

"Alatako ni mo jẹ tẹlẹ fun Buhari ko to di pe erongba sise saa kẹta de, eyi ti asaaju kan tẹlẹ nilẹ yii kuna lati gbe kalẹ. Mo mọ Buhari pe ko lee gbinyanju iru rẹ laelae."