You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2020 Events: Àwọn ìròyìn tó yẹ kẹ máa fojú sọ́nà fún rèé lọ́dún yìí
Ọdun 2020 yii jẹ ọdun ti awọn eniyan kan ti n pariwo rẹ, ti wọn si ti ni afojusun fun lati ọjọ pipẹ.
Nitori naa, ni a ṣe ṣe akojọpọ diẹ lara awọn iṣẹlẹ ti ẹ le fojusọna fun l'ọdun 2020.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bẹrẹ lati agbo oṣelu, sagbo faaji, Naijiria si Cameroon, Ghana, ati gbogbo agbaye. Eyi ni diẹ lara awọn nkan ti ẹ le fojusọna fun l'ọdun 2020.
Eto idibo 2020
Eto idibo Ghana:
Ọdun yii jẹ ọdun ibo didi, a o si bẹrẹ pẹlu orilẹede Ghana nibi ti wọn yoo ti ṣe eto idibo aarẹ wọn l'ọdun yii.
Aarẹ Nana Akufo-Addo n dije fun ipo naa fun igba keji, ṣugbọn o ni iṣẹ pupọ lati ṣe lati mu ki awọn eniyan o wo ọdọ̀ rẹ, bakan naa ni yoo maa fi iga-gbaga pẹlu aarẹ tẹlẹ, John Mahama t'oun naa n ṣẹju si ipo naa.
Ibeere to wa n gba ọkan awọn eeyan ni pe, ṣe iṣẹlẹ to waye l'ọdun 2016 yoo tun waye bi lọdun 2020?
Eto idibo America:
Oriṣiriṣi iṣẹlẹ lo ti ṣẹlẹ ni orilẹede America lati igba ti wọn ti d'ibo yan Donald Trump sipo aarẹ l'ọdun 2016.
Lọwọlọwọ, pipa ti wọn pa ọgagun kan lorilẹede Iran, Ọgagun Qasem Soleimani ti olu ileeṣẹ ologun America, Pentagon, sọ pe AArẹ Trump lo paṣẹ fun awọn lati pa, ni iroyin to gbaju-gbaja ju l'agbaye.
Ṣugbọn, Donald Trump ti bẹrẹ ipolongo ibo fun eto idibo aarẹ ti yoo waye l'oṣu Kọkanla, ọdun 2020. O ku ki a mọ boya yoo wọle saa keji si 'White House' abi bẹẹ kọ.
Opin iyọnipo nilẹ America
Yatọ s'eto idibo, ile aṣofin America wa laarin gbungbun igbesẹ lati yọ Aarẹ Trump nipo, nitori ipe kan to pe aarẹ Ukraine. Ti wọn si fi ẹsun kan Trump pe, o ṣi ipo rẹ lo.
Ile aṣofin kekere ti yọ ọ nipo, Aarẹ Trump si ni aarẹ kẹta ti orukọ rẹ wọ inu iwe itan awọn aarẹ America ti wọn yọ nipo.
Amọ nkan ti ọpọlọpọ n duro o de ni boya ile aṣofin agba yoo fi ontẹ lu iyọnipo rẹ.
Eto idibo orilẹede Somalia:
Orilẹede Somalia yoo dibo aarẹ miran l'ọdun yii.
Ohun to mu ki eto idibo naa o ṣe e tọka si ni pe, igba akọkọ niyii lati aadọta ọdun sẹyin ti awọn ọmọ orilẹede naa yoo l'anfaani lati dibo yan ẹni to wu wọn, dipo bi awọn aṣoju ṣe maa n ba wọn dibo tẹlẹ.
IGBEYAWO TI YOO MI IGBORO TITI NI NAIJIRIA !!!
Oya, ẹ maa palẹmọ fun #Assurance2020
Gbaju-gbaja olorin takasufe e, Davido, ti ṣetan lati gbe ololufẹ rẹ, to tun jẹ iya ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Chioma, niyawo l'ọdun yii, lẹyin to fun un ni oruka adehun nilu London l'ọdun 2019.
Igbeyawo gbajumọ miran ti ifojusọna tun wa fun ni laarin Khafi Kareem ati Ghedoni Ekpata.
Idije ere idaraya l'ọdun 2020:
African Nations Championship
Oṣu Kẹrin ọdun yii bakan naa ni orilẹede Cameroon yoo gbalejo idije ife ẹyẹ awọn akọni nilẹ adulawọ, African Nations Championship.
Idije naa ni yoo duro gẹgẹ bi idanwo fun igbimọ to ṣeto idije naa lori bi igbalejo idije African Nations Cup yoo ṣe ri l'ọdun 2021.
Euro Cup
Idije ere idaraya miran ti oju tun wa lara rẹ ni Euro 2020, ti yoo waye l'oṣu Kẹrin bakan naa.
Idije naa yoo ko gbogbo orilẹede ilẹ Yuroopu pọ lati gba bọọlu.
Brexit
Iṣẹlẹ nla miran ta tun maa foju sọna fun lọdun 2020 tun ni bi orilẹede Britain ṣe fẹ ẹ kuro ninu ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu.
Igbesẹ naa ti bẹrẹ lati ọdun 2016 nilẹ Gẹẹsi, ti wọn si ti pinnu pe awọn yoo kuro. L'ọdun yii, o yẹ ki gbogbo rẹ yanju paapa lẹyin ti Boris Johnson wọle gẹgẹ bi Olootu ijọba lasiko idibo gbogboogbo to kọja.
Awọn iroyin nipa eto ọrọ aje
Eco currency
L'opin ọdun 2019, Aarẹ France, Emmanuel Macron kede pe l'ọdun 2020, awọn yoo ṣe owo 'ECO currency' fun awọn orilẹede Africa to n sọ ede Faranse, to si n na cefas yoo ma a na.
Orilẹede Ghana naa ni oun n'ifẹ si eto yii, nitori pe awọn orilẹede to wa ni Iwọ Oorun Africa ti n jiroro lati maa na owo kan naa, gẹgẹ bi ọna lari ran eto okoowo lọwọ.
Visa Free Wiwọ Naijiria lai ni 'visa'
Aarẹ Muhammadu Buhari kede l'ọdun to kọja pe oun yoo jẹ ki awọn ọmọ ilẹ Africa o maa wọ Naijiria, ti wọn yoo si gba iwe irinna 'visa' ti wọn ba wọle. O ni eyi yoo fi aaye gba kata-kara.
Lati igba naa ni wọn ti ṣe alaye lọpọlọpọ lori ọna ti wọn yoo gbe e gba, ṣugbọn awọn eniyan ṣi n wo bi yoo ṣe ri.
Afikun owo ori
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n wo bi nkan yoo ṣe ri l'ọdun 2020 fun awọn nkan bi i ọja rira lori ayelujara, ati fifi owo ranṣẹ nilana igbalode, ti afikun de ba owo ori wọn.
Rogbodiyan Anglophone ni Cameroon
Kini yoo ṣẹlẹ nipa rogbodiyan to n waye ni Cameroon, ati ni agbegbe Anglophone , eyi to ti bẹrẹ lati ọdun 2017, to si yọri si iku ọpọ eniyan?
Lọdun to kọja, Aarẹ Paul Biya ṣe ijiroro gbogboogbo, ati awọn nkan miran to tun ṣe lati ri pe alaafia jọba ni agbegbe naa.
Awọn kan sọ pe bo ṣe yẹ ki nkan o ri niyẹn, ṣugbọn awọn kan ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi nkan ti oloyinbo n pe ni 'smoke and mirrors'.
'Vision 2020'
Ọpọlọpọ ijọba kaakiri agbaye ninu ikini ọdun tuntun wọn lo ṣe ileri awọn nkan ti wọn yoo ṣe lati mu idagbasoke ba orilẹede wọn.
Fun Naijiria, Aarẹ Buhari ṣeleri pe oun yoo pari awọn oju ọna, kọle fun araalu, ati awọn nkan miran l'ọdun 2020.
Afojusun Aarẹ Nana Akufo-Addo ni pe orilẹede Ghana yoo de ipo giga ni 2020.
Aarẹ Cameroon naa ṣeleri lati koju awọn to ya ara wọn kuro ni Cameroon, to si kọ lati yọnda nkan ijagun wọn. O sọ pe Cameroon tuntun ti yoo faramọ bi nkan ṣe ri lasiko yii, ati afojusun fun ọjọ iwaju, ti n bẹrẹ.