Naira Marley: Pásítọ̀ Omatsola tún kìlọ̀ fáwọn ọ̀dọ́ láti yé pe ara wọn ní Marlians

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja olorin takasufe, Afeez Fashola ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley, ti fesi si ọrọ Pasitọ Chris Omashola to pe ni ẹlẹmi Eṣu.

Ojiṣẹ Ọlọrun naa ti sọ tẹlẹ pe, Ọlọrun lo fi iran han oun pe ẹlẹmi Eṣu ni Naira Marley.

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ @omo_billionaire loju opo Twitter, lo bi awọn eeyan leere pe kin ni idajọ lori ọrọ pasitọ Omashola ati Naira Marley.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin naa ni Naira Marley funra rẹ fi ọrọ kan naa lede loju opo Twitter tiẹ naa.

Ṣugbọn orin ni Naira Marley fi fesi si ọrọ yii lẹyin to sọ pe ''Se bi omo jesu niwo, gbese ko Tesumole 🎶.''

Ero ọpọlọpọ awọn ololufẹ Naira Marley lo jọra wọn lori ọrọ naa, n ṣe ni awọn naa fi orin ''Se bi omo jesu niwo, gbese ko Tesumole 🎶'' bọ ẹnu ni idahun wọn si esi Naira Marley.

Amọ, ero awọn kan ṣọtọọtọ lori ọrọ naa, fun apẹrẹ, @funshi ni oniyẹyẹ ni pasitọ Omashola, o ni pasitọ naa ko riran pe Fashola Azeez lẹmi Eṣu.

Ẹlomiran, @mubaraq_a tun kin ọrọ @funshi lẹyin, o ni Naira Marley nikan ni Ọlọrun fihan ojiṣẹ Ọlọrun naa.

Epe rabandẹ lawọn kan tiẹ n fi ranṣẹ si pasitọ Omashola, wọn ni ko mọ ohun to n sọ.

Laipẹ yii ni Pasitọ Omashola sọrọ loju opo Twitter rẹ, nibi ti o ti kọ orukọ awọn eeyan to ro pe wọn ko le wọ ijọba ọrun ninu eyi ti Naira Marley wa loke tente.

Pasitọ Omoshola fikun ọrọ rẹ pe Naira Marley ni lati ronu piwada ni kiakia ko too pẹ fun un.

O ni awọn orin ti Naira Marley n kọ ni imisi Eṣu ninu, eyi to le ṣakoba fun ọjọ iwaju ati ayanmọ awọn ọdọ ni Naijira.

Bakan naa ni ojiṣẹ Ọlọrun Omoshola kilọ fawọn ọdọ wi pe, ki wọn ye pe ara wọn ni ''Marlians.''