You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Van Persie vs Solskjaer: Ole bínú tán, ó lóun ò mọ Van Persie rí, bẹ́l kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ̀rọ̀ s'óun
Bi oju akata ba lewo, ẹnu adiẹ kọ la o ti gbọ. Bayii ni akọnimọọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ṣe fesi si ọrọ ti ẹleṣẹ ayo tẹlẹ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Man U, Robin van Persie.
Van Persie lo bu ẹnu atẹ lu bi Solskjaer ṣe n rẹrin lasiko ti o n dahun ibeere awọn akọroyin lẹyin ti Arsenal ṣina iya fun Man U tan.
Van Persie kii ṣe asiko ti ẹgbẹ agbabọọlu Man U ṣẹṣẹ fidi rẹmi tan lo yẹ ki Ole maa rẹrin nigba to n dahun ibeere awọn akoroyin.
Amọ ọrọ yii ko bọ si ibi to dara lara Ole, nisẹ lo tutọ soke to si fi oju gba a.
''Mi o mọ Van Persie ri, oun naa ko si mọ mi, nitorinaa Van Persie ko lẹtọọ lati ma tako ọna ti mo n gba dari ikọ Man U,'' Solskjaer lo sọ bẹẹ.
Solskjaer tun tẹsiwaju, o ni ''Van Persie gba aṣo igbabọọlu oun to ni nọmba ''20'', ohun kan to maa ri gba lọwọ mi niyẹn.''
Ọrọ yii ti di iṣu ata yan-an yan-an loju opo Twitter nibi ti ọpọ ti bẹrẹ si ni fi Ole ati Van Persie we ara wọn nigba ti wọn gba bọọlu fun ikọ Man U.
Awọn ni Van Persie dantọ ju Ole lọ nigba to fi ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Man bo tilẹ jẹ pe akoko to lo ko to ti Ole.
Amọ, awọn mii fi aake kọri, wọn ni Ole kii ṣẹgbẹ Van Persie ni gbogbo ọna pẹlu ohun nla to gbe ṣe nigba to wa ni Man U.