You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé Arúgbó Saraki: Èyí ni ìdí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fí wó ìlè arúgbó ní ìdàjí
Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣalaye idi tawọn fi gbe igbesẹ wiwo ile arugbo nilu Ilorin.
Kọmisana feto iroyin nipinlẹ naa Murtala Olanrewaju sọ pe awọn ko fẹ ki ikọlu waye lawọn fi wo ile naa loruganjọ.
Ninu atẹjade kan ti o fi sọwọ sawọn akọroyin o sọ pe lasuba ọjọbọ lawọn bẹrẹ si ni wo ile naa tawọn agbofinro si duro wamu lalai doju ija kọ awọn to n tawọn laya.
Olanrewaju tun sọ ninu ọrọ rẹ pe ko si ootọ ninu ọrọ tawọn alatilẹyin Saraki n gbe ka pe ile ẹjọ ti paṣẹ kawọn ma fọwọ kan ile naa
''A ko ri iwe kankan gba lati ọdọ ile ẹjọ ṣaaju asiko ta fi bẹrẹ si ni wo ile naa''
O wa parọwa sawọn ara ilu lati bọwọ fofin ki wọn si ma ṣe gbọ ọrọ ahesọ to le ṣakoba fun alaafia ipinlẹ naa.
Bi a ko ba gbagbe awọn alatilẹyin Saraki to wa si ile arugbo naa ti wọn si ba akọroyin wa sọrọ sọ pe ijọba keti ikun si aṣẹ ile ẹjọ to ni ki wọn ma fọwọ kan ile arugbo Olusola Saraki
Wíwó Ilé Arúgbó kò lè yọ ìfẹ Saraki kúrò lọkàn aráàlú- Alága PDP
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọrọ lori bi ijọba ipinlẹ Kwara ṣe wo Ile Arugbo lulẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC, Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP,Ọgbẹni Kola Shittu ṣalaye pe wiwo ti ijọba wo Ile Arugbo ko le mu ifẹ awọn arugbo kuro lọkan Saraki.
Shittu ni bẹẹ si ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP naa ko ni jakan ninu ifẹ ti wọn ni si Saraki nitori ile ti wọn wo yi.
O ṣalaye pe Bukola Saraki gan an ni ọrọ naa kan julọ, amọ ohun to ba ti ba oju, o ti ba imu.
''Ko si ohun ti ẹgbẹ PDP fẹ ṣe lori ọrọ Ile Arugbo ti ijọba wo, PDP ko ni tori rẹ lọ si ile ẹjọ,'' Ọgbẹni Shittu lo woye bẹẹ.
O ni ohun ribiribi ti Oloye ṣe si ipinlẹ Kwara ati orilẹede Naijiria lapaapọ ju ki wọn maa gba ilẹ rẹ lọ.
Alaga PDP naa sọ pe ohun to yẹ ki ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sẹ ni pe ko paṣẹ ki ijọba gba owo ilẹ naa lọwọ awọn ẹbi Oloye to ba tiẹ jẹ pe Oloye ko sanwo ilẹ ọhun nigba naa.
O fikun ọrọ rẹ pe ẹka ijọba to n ri si ọrọ ilẹ naa lo kọwọ bọ iwe to sọ ilẹ naa di dukia Oloye nigba naa.
Ki lawọn alatilẹyin Saraki sọ?
Awọn eeyan to jẹ awọn alatilẹyin Bukola Saraki tu itọ soke foju gba a lori bi ijọba ipinlẹ Kwara ṣe wo ile Arugbo lulẹ laarọ Ọjọbọ niluu Ilorin.
Awọn eeyan naa ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ko laṣẹ lati wo ile ọhun nitori ọrọ ile naa wa nile ẹjọ.
Amọ ijọba sọ pe ọna aitọ ni Oloye Olusola Saraki fi gba ilẹ naa nigba naa nitori ko si akọsilẹ kankan to ṣafihan pe o sanwo fun ijọba.
Wọn ni ijọba to wa lode nipinlẹ Kwara n fi ibi su oloore pẹlu bi o ṣe wo ile arugbo lulẹ.
- A gbẹ́sẹ̀ lé ilé kan tó jẹ́ ti Bukola Saraki, torí àpò ìjọba ló ti mú owó sanwó ilẹ̀ - Ilé aṣòfin
- Saraki: Ìwà àrékérekè ni ilé mi tí EFCC tì pa
- Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
Wọ́n ti ti ilé ìjọba Kwara pa ní Ilọrin nítorí ọ̀rọ̀ ilé Arúgbó!
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lasiko yii ni pe wọn ti ile ijọba pa ni GRA ni Ilorin ni Kwara.
Wọn ni ijọba paṣẹ pe ki onikaluku oṣiṣẹ ile ijọba gbe ile rẹ lasiko yii nitori wahala.
Akọroyin BBC to wa ni Ilorin bayii ṣalaye pe ko si ẹni to le wọle tabi jade lasiko yii nile ijọba ni Ilorin.
O ni wọn ko jẹ ki ẹnikẹni sunmọ tosi ẹnu ọna ibẹ rara nitori pe ẹru n ba wọn pe ki iwọde tabi biba nkan jẹ ma lọ ṣẹlẹ lataari ile Arugbo ti wọn wo ni idaji oni.
Kini o ti ṣẹlẹ ṣeyin?
Lẹ́yìn ọ rẹyìn, ìjọba Kwara wó Ilé Arugbó Saraki lulẹ̀ ní Ilorin
Lẹyin ọ rẹyin, ijọba ipinlẹ Kwara ti pada wo 'Ile Arugbo' to wa ni ilu Ilorin.
Ile yii ni agbaọjẹ oloṣelu to ti di oloogbe, Oloye Olusọla Saraki kọ fun ra rẹ, eleyi ti wọn maa n fi n ṣe iranwọ fun awọn eeyan ti ko ri ọwọ họri.
Iroyin ti tan kalẹ kaakiri lati bi ọjọ melo kan pe ijọba ti ko katakata debi ile naa lati daa wo, amọ, laarọ oni Ọjọbọ ni ijọba pada wo ile naa.
- A gbẹ́sẹ̀ lé ilé kan tó jẹ́ ti Bukola Saraki, torí àpò ìjọba ló ti mú owó sanwó ilẹ̀ - Ilé aṣòfin
- Saraki: Ìwà àrékérekè ni ilé mi tí EFCC tì pa
- Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
Atẹjade kan ti olori ajọ to n ri si ọrọ ilẹ nipinlẹ Kwara, Ibrahim Salman fi sita ṣalaye pe ijọba ti ra ilẹ ti ile ọhun wa lori rẹ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin lati kọ olu ile iṣẹ ijọba si ori rẹ.
Ọgbẹni Salman ṣalaye pe ijọba yi ero rẹ pada lori ilẹ naa lọdun 1980 pẹlu erongba lati kọ ile iwosan fawọn oṣiṣẹ ijọba sori ilẹ naa.
O ni ọdun 1982 gan an ni ijọbakọ ile iwosan sori ilẹ naa pẹlu erongba lati fi ilẹ to ku kọ ile iwosan nla lọjọ iwaju.
Ọgbẹni Salman sọ siwaju sii ninu atẹjade naa pe lojiji ni ile iṣẹ Asa Investment ṣaa deedee bu ninu ilẹ ilẹ naa lati lo fun okowo lọna aitọ.
Ṣugbọn o ṣalaye ninu atẹjade naa pe ko si akọsilẹ wi pe wọn sanwo fun ilẹ ti wọn gba ọhun.
O ni bayii ni ile iṣẹ naa tẹsiwaju ti wọn si kọ Ile Arugbo si ori ilẹ naa nibi ti ijọba ya sọtọ fun garaaji igbekọ si ati ibi ti ijọba tun fẹ kọ ile iwosan nla si lọjọ iwaju.
Olori ajọ to n ri si ọrọ ilẹ nipinlẹ Kwara idi niyii ti ijọba ṣe wo ile naa lẹyin ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbaṣẹ lati gba ilẹ naa pada.