You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayodele Fayose: Ẹ̀yin ọ̀tá mi, ẹ lọ dì mọ́ òpò ina lọ́dún 2020
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹri, Ayodele Fayose lo ti fi eebu ransẹ si awọn to n pẹgan rẹ nise ti ọdun tuntun bẹrẹ naa.
Lori oju opo Twitter rẹ ni Fayose ti ki awọn ololufẹ rẹ ku ọdun tuntun, amọ to ni oun jẹ ẹfọri fun awọn to jẹ ọta oun.
Eyi ko sẹyin bi awọn kan ṣe bu ẹnu atẹ lu lẹyin ti fidio jade nibi ti o ti n jo pẹlu oyinbo ni ilẹ okeere to ti gba beeli pe oun fẹ lọ gba iwosan fun ara oun.
Amo Fayose ni ayẹwọ ara ni oun lo se e, oun ko dubulẹ aisan, nitori naa oun laṣẹ lati jo ati y ninu ọdun tuntun naa.