Otedola Bridge accident: Èèyàn méjì bá ìjàmbá ọ̀kọ̀ tó ṣẹlẹ̀ lórí afárá Otedola lọ

Eeyan meji ti dero ọrun ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lori afara Otedola lopopona marosẹ ilu Eko si Ibadan lọjọ Satide.

Ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ lẹyin ti ọkọ nla kan to ko okuta ikọle kọlu ọkọ Lexus agbera pa lori afara ọhun.

Ọga ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri niluu Eko, Ọmọwe Oluwafemi Oke-Osanyintolu ṣalaye pe awakọ nla naa fi ọkọ rẹ kọlu odi to wa laarin ọna.

Ọgbẹni Oke-Osanyintolu sọ pe ọkọ to ko okuta ikọle ọhun ja si meji lẹyin to kọlu odi to wa laarin ọna, ti ori ọkọ naa si jabọ lati ori afara.

O ṣalaye pe awọn meji to mori bọ ninu iṣẹlẹ naa gba itọju lẹsẹkẹsẹ, nigba ti ẹni to farapa ju ti lọ si ile iwosan fun itọju to peye.

Ọga LASEMA ni ajọ naa ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe ijamba ọkọ ọhun ko da sunkẹrẹ fakẹrẹ silẹ lopopona Eko si Ibadan.