Brighton vs Tottenham: Aṣọ́lé Tottenham, Hugo Lloris dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn ìyà àjẹtúnjẹ lórí pápá Brighton

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii. Kaka ko san fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, niṣe lo buru si o.

Ẹgbẹ agbabọọlu Brighton & Hove Albion lo ṣe Tottenham bi ọṣẹ tii ṣoju ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League lọjọ Abamẹta.

Ami ayo mẹta ọtọọtọ ni wọn Brighton fi ṣagba Tottenham eleyi to jẹ iyanlẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu.

Balogun ati aṣọle ikọ Tottenham, Hugo Lloris lo kọkọ tasẹ agẹrẹ bi Tacha lo ba mu bọọlu bọ sinu awọn ara rẹ.

Laipẹ ni aṣọle fọwọ ṣeeṣe debi pe wọn ni lati gbe lọ sile iwosan lati ori papa.

Ṣugbọn bi iya nla ba gbeni sanlẹ, kekere a gori ẹni ni Brighton fi ṣe fun Tottenham lẹyin ti wọn fi ọba lee pẹlu goolu meji.

Lẹyin ọ rẹyin, Brighton ṣina iya fun Tottenham pẹlu ami ayo mẹta sodo lairo tẹlẹ.