BBNaija: Kiki Osinbajo gbóṣùbà fún Seyi Awolowo, MC Oluomo gbárùkù ti Mike

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ti eegun ni ba mọọ jo, ori a ya atọkun. Gẹgẹ bẹẹ lọrọ ri pẹlu ọkan lara ọmọ igbakeji Aarẹ orilẹeede Naijiria, Kiki Osinbajo pẹlu ọrọ to sọ nipa eto agbelewo BBNaija.

Kiki to jẹ ọmọ ọmọ ọmọ Oloye Obafemi Awolowo gẹgẹ bi Seyi na ṣe jẹ to si jẹ ọkan lara awọn oludije ninu ile BBNaija ni Kiki sọ pe Seyi ti ṣe nnkan iwuri lati igba to ti wa nilu ile.

Kiki to sọrọ loju opo Instagram rẹ, lo rọ awọn eeyan lati dibo fun Seyi nibayii to kudiẹ ki eto naa pari.

Ẹnikan ninu Seyi tabi Mike Edward, Mercy Eke, Chemeka 'Frodd' Okoye, ati Kola 'Omashola' Oburoh ni yoo jawe olubori lori eto ọhun lọjọ Aiku.

Ṣugbọn bi ọrọ gangan an lọrọ ọhun, nitori alaga awọn awakọ nipinlẹ Eko, Musiliu Ayinde Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ ni tirẹ ni Mike loun dibo fun un.

Bakan naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati dibo fun Mike ko le wọle.

Koda MC Oluọmọ kọ nọmba Mike gadagba sori opo Instagram rẹ fawọn ololufẹ rẹ pe ki wọn dibo fun Mike.