You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kaduna Kidnapping - Ọmọ iléèwé mẹfà pẹlú Olùkọ méjì ni wọn jígbé ni Kaduna.
Awọn Ọlọpaa ni Ipinlẹ Kaduna ti fi idi ijinigbe awọn ọmọ ileewe mẹfa mulẹ.
Awọn Ọlọpaa sọ pe níṣe ni awọn ajinigbe naa yabo ile iwe naa pẹlu ibọn .
Ileewe naa jẹ eyi ti o ni ileegbe ti o si wa ni odi ilu naa .
Ni itosi Kakau DajiVillage ni Ijọba Ibilẹ Chikun ni ile iwe naa wa.
Ni Owurọ kutukutu ọjọbọ ọsẹ yii ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ti wọn si tun ji Olukọ meji gbe pelu.
Ajọ Olọpaa ni wọn ti da awọn ti o risi jijini gbe ẹka ajọ naa lati bẹrẹ si fimu finlẹ lati doola ẹmi awọn ti wọn jigbe naa.
Bakan naa ni Ọlọpaa ti wa kesi gbogbo awọn ti o ni ile iwe aladani lati sowọpọ pelu wọn lojuna ati dẹkun iru iṣẹlẹ bẹẹ.
Ọlọpaa wa ni pe ijiya nla n bẹ fun ẹnikẹni ti ade ori ọrọ naa ba ṣimọ.