You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Premier League: FIFA f'òfin de Chelsea kí wọ́n má lè ra agbábọ́ọ̀lù
Ikọ Chelsea ko ni lanfani lati ra agbabọọlu kankan titi yoo fi di ipari oṣun kinni ọdun to n bọ, lẹyin ti ajọ FIFA f'ofin de ẹgbẹ agbabọọlu naa.
FIFA f'ẹsun kan Chelsea pe wọn tapa sofin ti o nii ṣe pẹlu rira awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu.
Ọrọ yii jẹyọ lẹyin iwadii ti FIFA ṣe lori bi Chelsea ṣe ra ọdọmọde ẹlẹsẹ ayo, Bertrand Traore ati awọn agbabọọlu miran ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun lọ.
Owo itanran to din diẹ ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu pọn-un ni ajọ FIFA ni ki Chelsea san.
Bakan naa, ajọ FIFA ni ki ajọ to n ri si ere bọọlu nilẹ Gẹẹsi, FA san owo to din dẹ ni ẹgbẹrun lọna irinwo pọn-un gẹgẹ bi owo itanran.
Ajọ FIFA ni Chelsea tapa sofin ninu bi wọn ṣe ara agbabọọlu mọkandinlọgbọn ninu agbabọọlu mejilelaadọrun ti wọn ṣe iwadi lori wọn.
Ṣugbọn ajọ FA ti ni ohun yoo pe ẹjọ ko tẹmi lọrun lori ọrọ naa.