Èyí làwọn èèyàn tí wọn kò gbọdọ̀ dọ̀bálẹ̀ fún ọba ní ilẹ̀ Yorùbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bibu ọwọ ati ọla fun gbogbo eeyan, yala awọn to ju eniyan lọ ni o tabi awọn ti wọn jẹ ẹgbẹ ẹni, jẹ ọkan pataki lara opo ọmọluabi ni ilẹ Yoruba.

Idọbalẹ jẹ ọkan pataki ọna ati fi eyi han ninu iṣe ati aṣa Yoruba.

Gbogbo ọmọ Yoruba lkunrin ni ẹtọ fun lati dọbalẹ fun ẹnikẹni to ba ju wọn lọ.

Awọn ọba, gẹgẹbi aṣa Yoruba ni o wa loke tente tabili agbekalẹ gbogbo lawujọ nitori pe ni kete ti wọn ba ti gun ori itẹ, labẹ aṣa Yoruba, wọn ti di baba fun gbogbo awọn to wa labẹ akoso iṣejọba wọn.

Idọbalẹ jẹ ara ọna ti a fi n bu ọla fun awọn ọba tabi adari. Oun ni Yoruba maa fi n wi pe, a kii duro ki ọba alade.

Eewọ ni lati bọ ọba lọwọ.

Ni ile Yoruba, o se koko ki awọn araalu bi o ti lẹ wu ti kere mọ tabi tobi, wọn gbọdọ foribalẹ fun ori ade ni ọkunrin tabi obinrin.

To da ifa fun pe “Ẹni to ba ri ọba fin, ni ọba n pa”

Sugbọn awọn eeyan kan wa to jẹ pe Asa, ẹsin ati iṣe wọn ko fi aye silẹ fun lati fi ori balẹ fun ori ade kankan ni ilẹ kaarọ ojire.

Saaju ni fọnran kan lu si ori ayelujara nibi ti agba ọjẹ kan ni ilu kan ti kọ lati dọnalẹ fun ori ade ilu naa.

Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ yii, ti wọn si ni ko tọna si aṣa ati ise ilẹ Yoruba.

BBC kan si awọn amoye nipa aṣa ati ise ilẹ Yoruba lati tan imọlẹ si ọrọ ati lati pese idahun si ibeere to ni “N jẹ awọn eeyan kan wa ti wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ori ade.

Baba Oluawo Yemi Elebuibon ba BBC Yoruba sọrọ, ti wọn si ṣalaye ni ẹkunrẹrẹ nipa awọn eeyan ti aṣa ati ipo wọn ko fi aye silẹ fun lati dọbalẹ fun ori ade.

Eeyan kan ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba ti wọn ba fẹ ki ẹmi rẹ gun

Ninu alayẹ, Elebuibon ni awọn eeyan kan wa ti wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba nitori oye ti wọn jẹ ati awọn etutu ti wọn se to sọ wọn di oloye.

O tẹsiwaju pe o ni awọn eeyan to jẹ pe wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba alade sugbọn ti wọn n gba idọbalẹ oba alade.

“Ti ẹ ba wo alaafin Oyo, to jẹ pe Oba to tobi ni, awọn iya mẹrin kan wa ni aafin to jẹ pe awọn ni wọn gba idọbalẹ alaafin, ti ki se oju gbangba.

“Awọn ijoye kan wa ti wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba, ti wọn ba fi le dọbalẹ fun ọba, wọn wa isubu rẹ ni, ko si irọ nibẹ.”

Elebuibon ni oun gẹgẹ bii eeyan kan, oun ko ki n dọbalẹ fun ọba niluu Osogbo nitori oun ni Araba fun ilu osogbo.

“Awọn eeyan yii, wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba ti wọn ba fẹ ki ẹmi ọba naa gun.

“Ti Ọba ba se iwadii toto, yoo mọ pe awọn eeyan kan ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba, aini imọ ni.

“Yatọ si oloye tabi eeyan kan to ni oro nla lara, awọn nikan ni wọn ni anfani yii lati ma le dọbalẹ.

“Ọpọ awọn olowo lo ma ni igberaga, ti wọn ko si ki n fun ọba ni iponlẹ.”

Ọba Ogboni ko gbọdọ dọbalẹ fun nitori etutu fun jijẹ Oba Ogboni ju ti ọba lọ

Ninu alaye Ọba Ogboni Igba Iwasẹ, Adeyinka Arifanlajogun ni oun gẹgẹ bii Ọba Ogboni, oun jẹ ọkan lara awọn ti wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba ilu nitori o lewu pupọ nitori awọn etutu ti Ogboni n se lo maa n da bi ti ọba ilu.

Arifanlajogun ni igba iwasẹ ni o ni kankan to so Ogboni ati Ọba papọ.

“Ni igba iwasẹ, Ogboni to ba fẹ dọbalẹ fun ọba ilu, o ni nnkan ti wọn gbọdọ yọ kuro lara eeyan bẹ, iyẹn to ba jẹ pe o se etutu

“Ogboni lo yan ọba ilu, ti Ogboni ba se etutu fun ọba ilu, ti Ọba naa ba wa se aṣemaṣe lori apere, ti wọn si fẹ le kuro ni ilu, awọn Ogboni nikan lo ni agbara lati yọ ọ kuro, ti wọn ba fẹ le Ọba, ọba Ogboni yoo lọ dọbalẹ fun Ọba naa, lẹyin ọjọ meje, ọba naa le waja.

O ni awọn ijoye kan naa wa ti wọn ko gbọdọ dọbalẹ fun ọba. o ni eyi kii ṣe igberaga rara, ilana ati agbekalẹ aṣa ni