You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria 2019 Election: Ààrẹ Buhari ní k'áwọn ọmọ Nàìjíríà dìbò yan ẹni tó wù wọ́n
Aarẹ Muhammmadu Buhari ni idibo aarẹ ati tile igbimọ aṣofin agba ọjọ Satide yoo lọ n'irọwọ rọsẹ, bẹẹ lo rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati jade dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Aarẹ sọrọ yii nigba to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ẹro amohun-maworan ti ijọba apapọ, NTA ati ile iṣẹ Radio Naijiria laarọ ọjọ Ẹti ṣaaju idibo ọjọ Abamẹta
Aarẹ Buhari awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti wa ni digbi lati daabo bo eeyan nibi ti wọn ba ti n dibo.
Aarẹ ko si iyi to ju ki awọn eeyan dibo fun olori ti wọn fẹ ko maa dari wọn lọ gẹgẹ ọmọ orilẹede tootọ.
Aarẹ Buhari fikun ọrọ pe ajọ eleto idibo INEC ti ṣetan lati ṣagbatẹru idibo ti yoo lọ ni irọwọ rọsẹ lọjọ Abamẹta.
Aarẹ tun fi da awọn onwoye loju pe ko si ewu rara fun wọn, o ni aabo to peye yoo wa fun wọn lọjọ idibo.
Aarẹ Buhari bawọn ọmọ Naijiria sọrọ lọsẹ to kọja ki ajọ eleto idibo INEC to sun ibo to yẹ ko waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji siwaju.