Nigeria 2019 Election: Ààrẹ Buhari ní k'áwọn ọmọ Nàìjíríà dìbò yan ẹni tó wù wọ́n
Oríṣun àwòrán, NTA
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Muhammadu sọrọ lori idibo ọjọ Satide
Aarẹ Muhammmadu Buhari ni idibo aarẹ ati tile igbimọ aṣofin agba ọjọ Satide yoo lọ n'irọwọ rọsẹ, bẹẹ lo rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati jade dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Aarẹ sọrọ yii nigba to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ẹro amohun-maworan ti ijọba apapọ, NTA ati ile iṣẹ Radio Naijiria laarọ ọjọ Ẹti ṣaaju idibo ọjọ Abamẹta
Aarẹ Buhari awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti wa ni digbi lati daabo bo eeyan nibi ti wọn ba ti n dibo.
Àkọlé fídíò, #NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí
Aarẹ ko si iyi to ju ki awọn eeyan dibo fun olori ti wọn fẹ ko maa dari wọn lọ gẹgẹ ọmọ orilẹede tootọ.