You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Man Utd v Juventus: Kíni ipadabọ Ronaldo sí Old Trafford yóò bí?
Ipadabọ agbabọọlu si ẹgbẹ to ti figba kan gba bọọlu fun ri a maa mu ero ọkan orisirisi wa.
Bẹẹ ni ọrọ yoo ri fun gbajugbaja agbabọọlu nni, Cristriano Ronaldo ti o ba koju ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lalẹ ọjọ isẹgun ninu idije Champions League pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ lati ẹgbẹ Juventus.
Manchester United ni Ronaldo ti fakọyọ ti o si ti di ilumọka agbabọọlu.
Loju opo Twitter rẹ,Ronaldo ni inu oun dun lati pada wa si Old Trafford.
Ronaldo darapọmọ Manchester United lati ẹgbẹ Sporting Lisbon fun miliọnu mejila poun o le die lọdun 2003.
Goolu méjídínlọ́gọ́fà lo gba wọ inu awn fun Manchester United ninu ifẹsẹwọnsẹ ọ́ọ̀dúnrún dín mẹjọ.
Ipade manigbagbe laarin Manchester United ati Juventus kan waye nigba ti wọn koju ninu ipele to pọwọ le asekagba idije Champions League lọdun 1999.
Ifẹsẹwọnsẹ ikẹyin laarin wọn waye ni 2003 nibi ti Man U ti gbewuro soju Juventus pẹlu ami ayo mẹta.
Ballon D'or: Ronaldo wà lára agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n yàn fún àmì ẹ̀yẹ
Agbaọjẹ agbabọọlu Cristiano Ronaldo wa lara awọn agbabọọlu ti wọn f'orukọ wọn lede ninu awọn ti wọn yoo gba ami ẹyẹ Ballon D'or ti ọdun 2018.
Ọpọ ro tẹlẹ pe orukọ Ronaldo le maa wa lara awọn orukọ agbabọọlu ti wọn yoo kede fun ami ẹyẹ naa nitori iwadi to n lọ lọwọ lori ẹsun ti arabinrin ilẹ Amẹrika kan fi kan an pe o fipa ba oun lo pọ lọdun 2009.
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Portugal Fernando Santos ko tilẹ fi orukọ Ronaldo s'ara awọn agbabọọlu ti yoo soju orilẹede naa ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn to n bọ pẹlu Scotland ati Poland nitori ẹsun kan naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ṣugbọn Ronaldo ti fesi pe oun ko jẹbi ẹsun ti obinrin naa fi kan oun.
Ẹwẹ, agbabọọlu fun ikọ Real Madrid to jẹ ọmọ orilẹede Croatia Luka Modric lo gba ami ẹyẹ FIFA gẹgẹ bi ọkunrin agbabọọlu to pegede julọ ni tootọ, ṣugbọn awọn kan ni oun kọ ni ami ẹyẹ naa tọsi.
Ọpọlọpọ ololufẹ ere bọọlu ti wọn fi ero wọn han loju opo Twitter ni wọn bu ẹnu atẹ lu igbẹsẹ ajọ FIFA lati gbe ami ẹyẹ naa fun Modric, fun apẹrẹ Vic Rattlehead ati Carter V sọ pe Cristiano Ronaldo ni ami ẹyẹ naa tọsi ju.
Ṣe ẹ mọ pe ẹkọ ẹlẹkọ lẹgba ẹlẹgba, nibi ti awọn kan ti sọ pe Modric ko yẹ fun ami ẹyẹ FIFA, bẹẹ naa lawọn kan ni agbabọọlu Modric lo pegede julọ lọwọ yii ninu gbogbo awọn agbabọọlu ọkunrin lagbaye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọkan lara awọn to sọ pe Modric gan ni ika to tọ si imu ti wọn fi n rin imu ni akọnimọọgba Real Madrid tẹlẹ ri Zinedine Zidane.
Zidane to sọrọ loju opo Twitter rẹ f'ọwọ sọya pe lọwọ yii o, Modric lo pegede julọ ninu awọn agbabọọlu ọkunrin lagbaye.
Isco ti oun naa jẹ ọkan lara awọn akẹgbẹ Modric ni ikọ Real Madrid ni oun naa ni akọni agbabọọlu to fakọyọ julọ lasiko yii.