You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iṣẹ́ ju iṣẹ́ lọ: Wọ́n ra Ronaldo ọmọ ọdún 33 ni £99m
Agbabọọlu iwaju fun ikọ Real Madrid, Cristiano Ronaldo darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Juventus lẹyin ti Juve san £99m fun Real Madrid to ti wa.
Ṣugbọn ọpọlọpọ ololufẹ ere bọọlu lo ti n sọ pe owo naa pọ lati na lori agbabọọlu to ti pe ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn.
Awọn kan ro pe ọjọ ori Ronaldo le ma gba laye lati fakọyọ fun ikọ Juventus fun igba pipẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ronaldo gba ayo 450 sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ 438 nigbati o wa pẹlu Real Madrid
O si gba ami ẹyẹ Idije Champions League pẹlu Real Madrid ni igba mẹrin.