#Russia 2018: Ta ni yóò gba ''golden boot'' ní Russia?

Idije fun agbabọọlu ti yoo gba ami ẹyẹ fun ẹni to gba bọọlu sawọn ju ''Golden Boot'' ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti gbona sii bayii bi idije naa ti wọ ipele to kangun si aṣekagba.

Ọgọ́jọ ayo o din mẹta ni awọn agbabọọlu ti gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ọgọta ti wọn gba lati igba ti idije naa ti bẹ̀rẹ̀.

Ẹlẹsẹ ayo to jẹ ọmọbibi ilẹ Gẹẹsi Harry Kane lo n siwaju ninu awọn ti wọn gba bọọlu sawọn ju ni Russia pẹlu ami ayo mẹfa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kane yoo ni anfani lati fi kun ami ayo rẹ nigba ti ilẹ Gẹẹsi ba koju Croatia ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba wọn l'Ọjọru.

Agbaọjẹ agbabọọlu Cristiano Ronaldo to jẹ ọmọbibi orilẹede Portugal gba ayo mẹrin sawọn ki orilẹede naa to lọ'le lati Russia.

Ẹlẹsẹ ayo Romelu Lukaku to n gba bọọlu fun Belgium naa ti gba ayo mẹrin sawọn, o si ni anfani lati fikun ami ayo rẹ nigbati Belgium ba koju France.

Ọmọ ilẹ Russia ti wọn n gbalejo idije ife ẹyẹ agbaye Denis Cheryshev naa wa lara awọn to ti gb'ayo mẹrin sawọn ni Russia.

Antoine Griezmann to jẹ agbabọọlu iwaju fun orilẹede France naa ko gbẹyin ninu awọn ẹlẹsẹ ayo lẹyin ti o ti gb'ayo mẹta wọle.

Kylian Mbappe ti oun naa jẹ ọmọbibi ilẹ France ni ami ayo mẹta ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ.

Diego Costa ti o ti d'ero ile bayi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Spain naa gb'ayo mẹta sawọn ki wọn to l'ọle lati Russia.