You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FIBA World Cup: D'Tigress tún fakọyọ lẹ́yìn tí wọ́n na Argentina
Ikọ agbabọọlu afọwọgba ti obirin Niajiria ti orukọ wọn njẹ D'Tigress tun ti fakọyọ ninu ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorilẹede Spain lẹyin ti wọn fagba han ikọ Argentina ayo marundinlọgọrin si aadọrin(75-70) ninu ifẹṣẹwọnsẹ keji wọn ninu idije naa.
Ẹ o ranti pe D'Tigress jẹwọ ara wọn nigba ti wọn lu ikọ orilẹede Turkey ni alubami ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn.
Ifẹsẹwọnsẹ naa koko bi oju ẹja bi awọn ikọ Naijiria ati Argentina ti n yi ara wọn sọtun sosi.
Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ sí:
Ikọ D'Tigress ni agbabọọlu afọwọgba akọkọ bayii ti wọn yoo jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn kọ gba ninu idije ife ẹyẹ agbaye.
Ẹwẹ, D'Tigress ti sọ Argentina dero ile lẹyin iya ti wọn fi jẹwọn.
Ikọ D'Tigress yoo koju orilẹede Greece bayii ni iplele kọmẹsẹọyọ ẹlẹni mẹjọ(quarter finals).
Ọpọlọpọ lo ti n ranṣẹ ikini ku oririre si awọn ọmọbinrin Naijiria yii ti wọn fakọyọ, koda ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria gan NFF ko gbẹyin.
Bakannaa ni ọgọrọ eeyan fi idunu wọn han loju opo twitter nibi ti wọn ti n ki D'Tigress ni mẹsan mẹwaa.
Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijria ni ko mọ nipa aṣeyọri awọn aramọda obinrin wọn yii.
Orukọ awọn mejila ti wọn ko lọ idije naa ni: Jasmine Nwajei, Adaora Elonu, Sarah Imovbioh, Sarah Ogoke, Elo Edema, Nkechi Akashili, Evelyn Akhator, Aisha Mohammed, Ezinne Kalu, Atonye Nyingifa, Cecilia Okoye ati Promise Amukamara
Fun anfani awọn ti ko mọ bii idije naa ṣe waye, awọn oun to ṣẹlẹ nigba idije naa ree.
Akọnimọọgba D'Tigress Otis Hughley ree nibi to ti n ṣe aṣepari iṣẹ lori igbaradi awọn ikọ obinrin naa fun idije naa.