You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ Bàbá Sala: Àwọn ènìyàn fẹ́ran Baba nìtorí apanilẹ́ẹ̀rín ni wọ́n
Ọpọ̀lọpọ̀ àgbà ọmọ yorùbá àti àwọn ọ̀dọ̀ yóò ránti gbajúgbajà òṣèré aláwàdà nnì, Moses Olaiya tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Baba Sala.
Àwọn tó jẹ́ olólùfẹ́ àwọn eré rẹ̀ náà kò sími láti sọ ipa pàtàkì tí àwọn àwàdà Bàbá Sala ń kó láti mú àwọn ènìyàn fùrù ara.
Eyi ni awọn ohun marun to lamilaaka nipa Baba Sala
- Ọjọ Kẹtadinlogun, Osu Karun, ọdun 1937 ni wọn bi Alagba Moses Ọlaiya Adejumọ ti gbogbo eniyan mọ si Baba Sala.
- Isẹ apanilẹrin ni wọn yan laayo, atiwipe Baba Sala lo kọkọ bẹrẹ isẹ amuludun ati orin takasufe lorilẹede Naijiria ni ọdun 1964, to si jẹ olukọ fun ọkan gboogi lara awọn adari orin juju ni orilẹede Naijiria, King Sunny Ade.
- Ile isẹ amohunmaworan akọkọ lorilẹede Naijiria, Western Nigeria Television (WNTV) lo se iranwọ fun Baba Sala to fi da ilumọọka gbajugbaja amuludun. Agoogo meje alẹ Ọjọru ni NTA Ibadan ma n gbe ere Baba Sala jade lori afẹfẹ, ti ọpọlọpọ eniyan si ma n salọ si ile lati lọ wọ ere naa ti wọn pe akọle rẹ ni Alawada Comedy Show.
- Lasiko ti Aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo wa lori aleefa, Baba Sala gba Ami Ẹyẹ ọlọla lorilẹede Naijiria, Member of di Order of di Niger (MON)ni ọdun 1978.
- Baba Sala tun gba Ami Ẹyẹ lati ọw Ile-isẹ Amohunmaworan ati Ile isẹ Iwe Iroyin Concord Press of Naijiria ni ọdun 1986.
Àwọn ará ìjọ́ Cherubim & Seraphim Movement sọ nípa olóògbe Moses Olaiya
Àwọn ọmọ àti ìyàwó olóògbé Moses Ọlaoluwa Adejumọ sọ pé ìwà ire sọ́ọ́ ní àwọn kọ lára ìgbé ayé Baba Sala.
Awọn abanikẹdun ko dawọ ikini duro ni ile oloogbe Moses Adejumo Olaiya ti gbogbo eeyan mọ si Baba Sala ni ilu Ilesa.
Ara, ọrẹ, aladugbo ati gbogbo mọlẹbi lo peju lese lati ṣe idaro oloogbe, Moses Ọlaoluwa Adejumọ ni ile rẹ to wa ni Lẹjọka Abiọla Avenue, Ileṣa.
Lowuro ọjọ aje ni ìròyìn tẹ̀ wa lọ́wọ́ pé gbajúgbajà òṣèré tíátà Yoruba ọkunrin nì, Alagba Moses Adejumọ gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Baba Sala jáde láyé, ni nnkan bi ago mẹwa alẹ ọjọ aiku .
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbẹnusọ fun agba ọjẹ osere naa, Isaac Haastrup,BBC Yoruba fidi ọrọ iku rẹ mule ati wi pe wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọsi ni ile iwosan Wesley Guild, nilu Ilesha.
Baba Sala jẹ Baba Adura ijọ Kẹrubu ati Serafu ẹka ti Idasa model Parish.
Isaac Haastrup ni ẹsẹ ko duro lati igba ti iroyin iku Baba ti lu jade.
''Ni se ni awọn ololufẹ Baba n wa ba wa kẹdun ni ile ati ile ijọsin wọn''
Ni igba to wa laye, Baba Sala jẹ ọgunnagbongbo ẹka ere idaraya lorileede Naijiria ti ọpọ awọn olorin ati osere tiata kose lọdọ rẹ́.
Ninu wọn la ti ri gbajugbaja akorin juju King Sunny Ade.
Awọn ọmọ Naijiria n daro Baba Sala
Mínísítà fún ìròyìn àti àṣà Alhaji Lai Muhammed lórúkọ ìjọba àpapọ̀ ní aláwàdà tí kò ṣeé fi wé ẹnikẹ́ni ni olóògbé Moses Olaiya jẹ́.
Nínú àtẹ̀jáde tí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ fọwọ́ sí, mínísítà fi ìbanújk hàn lórí ìpapòdà Bàbá Sala.
Loju opo Twitter ati kaakiri ẹrọ ayelujara lawọn ọmọ Naijiria ti n daro rẹ
Ọmọ bibi ilu Ilesha ni alagba Moses Olaiya ti a si bi ni ọdun 1936.
Lati bi ọdun melo kan sẹyin ni a ti n gbọ awuyewuye lori iku Baba Sala sugbọn Baba ni anfaani ẹmi gigun titi di ana.
Baba Sala wa lara awọn to kọkọ mu ẹrẹ sinima wa si orileede Naijiria pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ bi Hubert Ogunde,Kola Ogunmola Oyin Adejobi ati Duro Ladipo.
Orin Highlife ni Baba Sala kọkọ n kọ ti o si da ẹgbẹ akọrin kan silẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Federal Rythym Dandies'' ki o to wa ya si ere tiata.
Akole Awọn ere ti Baba Sala se nigba aye rẹ
- Orun Mooru (1982)
- Aare Agbaye (1983)
- Mosebolatan (1985)
- Obee Gbona (1989)
- Diamond (1990 Home video )
- Agba Man (1992, Home Video)
- Return Match (1993, Home Video)
- Ana Gomina (1996, home video, )
- Tokunbo (1985, TV)