Asaba 2018: Nàíjíríà ṣe ipò kẹ́ta ní ìdíje

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipo kẹta ni orilẹede fi pari nibi idije ere idaraya ilẹ Afirika to pari ni ọjọ aiku.
Ikọ orilẹede Naijiria nibi idije naa gba apapọ ami ẹyẹ mọkandinlogun, ninu eyi ti mẹsan ti jẹ goolu, marun jẹ silifa, marun si jẹ baba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Orilẹede Kenya lo ṣe ipo kinni pẹlu goolu mọkanla, silifa mẹfa, ati baba meji ti orilẹede South Africa si ṣe ipo keji pẹlu goolu mẹsan, silifa mẹtala, ati baba mẹjọ.
Glory Nathaniel gba goolu ninu ere asafogi onirinwo mita, (400meters hurdles), ti Grace Anigbata naa si tun gba goolu ninu idije ilẹ fifo, (triple jump).

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa lawọn obinrin tun gba goolu ninu ere asa gbagi onirinwo mita.








