Aisha Buhari, ìyàwó ààrẹ Gambia Fatoumatta Bah-Barrow ṣe ọjọ ìbí níléèwòsàn l'Ábújá

Oríṣun àwòrán, @Laurestar
Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ti darapọ mọ iyawo aarẹ orilẹede Gambia, Fatoumatta Bah-Barrow lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹrinlelogoji rẹ nilu Abuja.
Gẹgẹ bii iroyin kan lori ikanni twitter oluranlọwọ aarẹ lori ọrọ iroyin ayelujara, Lauretta Onoche, Aisha buhari ati Fatoumatta Bah-Barrow ṣe pọpọsinsin ọjọ ibi naa pẹlu abẹwo si ileewosan Maitama nilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, @Laurestar
Nileewosan naa ni iyawo aarẹ orilẹede Gambia, Fatoumatta Bah-Barrow ti ba awọn obinrin ati ọmọde dawọọ idunnu ti wọn si tun ge akara oyinbo rẹ ni ile aarẹ, Aso Rock nilu Abuja kan naa.
Ni ọjọ karun oṣu kẹjọ ọdun 1974 ni wọn bi Fatoumatta Bah-Barrow ni ilu Banjul tii ṣe olu ilu orilẹede Gambia.

Oríṣun àwòrán, @Laurestar
Ni oju opo twitter tirẹ, iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ni idi ti Fatoumatta Bah-Barrow fi sami ayajọ ibi rẹ lorilẹede Naijiria ko se lori bi ọjọ ibi rẹ ṣe ṣe kongẹ abẹwo iyawo aarẹ Gambia naa si Naijiria lati bẹ awọn akẹkọ orilẹede naa marun kan wo nileewe girama aladani kan lorilẹede Naijiria.








