Àwọn opó 150 gba irinṣẹ́ ọrọ̀ ajé nílú Ìwó

Awọn opo n gba irinsẹ wọn
Àkọlé àwòrán, Awọn ohun elo iṣẹ alabọde bii ẹrọ ilọta, ẹrọ guguru, ẹrọ iṣerun, ẹrọ iranṣọ, ati owo lati fi bẹrẹ iṣẹ kereje-kereje ni awọn opo naa tẹwọ gba

"Ohun ti awa opo n dojukọ lawujọ kii ṣe kekere rara. Ọpọ to ri nkan mu ṣe ọrọ lawujọ ni kii ranti awa opo."

Eyi ni ipe awọn opo nipinlẹ Ọṣun lasiko ti awọn aadọjọ opo kan n tẹwọ gba ohun elo amayedẹrun nipinlẹ Ọṣun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Buhari, Saraki, Dangote, abẹ́ mi ni wọ́n wà'

Awọn ohun elo iṣẹ alabọde bii ẹrọ ilọta, ẹrọ guguru, ẹrọ iṣerun, ẹrọ iranṣọ, ati owo lati fi bẹrẹ iṣẹ kereje-kereje ni awọn opo naa tẹwọ gba nibi eto kan ti ajọ kan ti kii ṣe tijọba gbe kalẹ ni ilu Iwo.

Diẹ lara awọn opo naa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe awọn opo n dojukọ ipenija to pọ lawujọ.

Arabinrin Toyin Tijani ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe, 'ọpọ awọn opo lo n da bukata atijẹ ati atimu ọmọ wọn gbọ.'

Awọn opo n gba irinsẹ wọn
Àkọlé àwòrán, Gbogbo awọn opo to janfani awọn ohun elo naa ni yoo wulo fáwọn lati da ileeṣẹ alabọde silẹ

Gbogbo awọn opo miran nibi eto naa to janfani awọn ohun elo naa bii arabinrin Racheal Taiwo ati Kudirat Rufai ni awọn ohun elo iṣẹ kerejekereje ti wọn fun awọn 'yoo wulo lati da ileeṣẹ alabọde silẹ lati maa bọ ẹbi awọn.'

Ninu ọrọ rẹ, alakoso eto igbayegbadun fawọn opo naa, Amofin Funmi Lamuye ni asiko to fun awọn ti eledumare ba ṣẹgi ọla fun lawujọ lati maa ranti awọn to ku diẹ kaato fun, paapaa julọ awọn opo.

Awọn opo n gba irinsẹ wọn

"Ohun ti mo fẹ lati ọdọ awọ opo wọnyi ni pe ki wọn maṣe ta awọn irinṣẹ ti a gbe le wọn lọwọ yii nitori eredi rẹ ni lati ṣan ọna atijẹ ati atimu funwọn, o si yẹ ki wọn loo bẹẹ gẹgẹ."