You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Man City kojú Chelsea fún ife ẹ̀yẹ Community Shield
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City bẹrẹ ìdíje pẹlu Chelsea ninu idije Community Shield loni ni papa iṣire Wembley ni ilu London.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Manchester City n kopa ninu idije naa gẹgẹ bii ẹgbẹ agbabọọlu to gba liigi saa to kọja nigba ti Chelsea n kopa gẹgẹ bii ikọ to gba ife ẹyẹ FA nilẹ Gẹẹsi.
Idije ife ẹyẹ Community Shield yii ni ifẹsẹwọnsẹ to maa n ṣe atọna fun saa liigi tuntun nilẹ Gẹẹsi.
Ni agogo mẹta ọjọ Isinmi ni o ń waye.
Idije yii ni yoo jẹ idanwo akọkọ fun olukọni tuntun fun ikọ Chelsea, Maurizio Sarri, lẹyin ti awọn alaṣẹ ikọ Chelsea le olukọni wọn tẹlẹ, Antonio Conte lọ ni ọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun yii.